Ìjọba gbọ́dọ̀ fi páńpẹ́ ọba mú CJN tẹlẹ̀, ìfipòsílẹ̀ kò tó – Huriwa

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ministry of Justice

Ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọ Naijiria, Human Right Writers Association of Nigeria ti sọ wipe ifiposilẹ nikan kọ ni ọrọ Olootu Eto idajọ ni Naijiria tẹlẹ nilo, o gbọdọ foju wina ofin.

Eyi ko ṣẹyin bi CJN tẹlẹ naa,Tanko Muhammed ṣe fi ipo silẹ ti wọn si naa olotu eto idajọ miran.

Muhammed lo fi ipo rẹ silẹ lori iroyin pe eto ilera rẹ ti mẹhẹ lẹyin ti wọn fẹsun lilo ọwọ awọn adajọ basubasu kan an.

Awọn adajọ agba mẹrinla ni ile ẹjọ to gaju ni Naijiria lo fẹsun iwa ibajẹ naa kan an.

Bakan naa ni ẹgbẹ ajafẹtọ naa ti kesi Ajọ to n risi ẹtọ awọn adajọ ni Naijiria ati ileẹjọ to n gbẹjọ iwa ibajẹ ni Naijiria, EfCC, ICPC ati NJC.

‘’Ni kiakia awọn ajọ to n gbẹjọ iwa ibajẹ yii gbọdọ ṣe iṣẹ wọn ni lori Tanko Muhammed to kọ iwe fi ipo rẹ silẹ.’’

‘’Wọn gbọdọ ṣe ayẹwọ finifini lori ẹsun ti wọn fi kan an, ti awọn adajọ agba naa to jẹ mẹrinla ba ni ẹri to daju.’’

‘’Tanko Muhammed naa gbọdọ foju wina ofin bi asaaju rẹ, Walter Onnoghen ṣe fi oju wina ofin lasiko iwadii ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kankan.’’

‘’Ti wọn ba ṣe iwadii Tanko nikan ni awọn ọmọ Naijiria to le gbagbọ ninu iṣejọba aarẹ Buhari pe lootọ ni wọn n gbogun iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria.’’

Ajọ Huriwa ni ti wọn ba ri pe o jẹbi ẹsun naa, ti wọn si fi jofin, eleyii yoo kọ awọn agbẹjọro miran ni ọgbọn lati maṣe hu iwa ibajẹ lawujọ mọ.

Adájọ́ àgbà Nàíjíríà kọ̀wé fipo sílẹ̀

Adajọ agba ni Naijiria, Ibrahim Tanko Muhammad ti kọwe fipo rẹ silẹ.

Eeyan kan ti ẹnu rẹ tọrọ ni ẹka eto idajọ ilẹ wa lo fidi isẹlẹ naa to BBC leti.

Iroyin naa ni alẹ ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹfa ọdun 2022 ni adajọ Muhammad kọwe fipo rẹ silẹ.

A gbọ pe igbesẹ bo se kọwe fipo silẹ ni wọn so mọ aawọ to wa laarin rẹ ati awọn adajọ jankanjankan mẹrinla ti wọn fi ẹsun aikunju osuwọn kan-an lọsẹ to kọja.

Amugbalẹgbẹ kan to sun mọ adajọ agba naa pẹkipẹki amọ ti ko fẹ ka darukọ ohun salaye pe adajọ Muhammad ti pasẹ pe ki adajọ ti ipo rẹ ga julọ nile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa gba akoso ẹka eto idajọ naa, ki wọn to kede adajọ agba tuntun fun orilẹede yii.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ministry of Justice

Wo oju ẹni tuntun ti yoo gba ipo adajọ agba Naijiria

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ministry of Justice

Wayi o. O seese ko jẹ pe adajọ to tẹle Ibrahim Tanko Muhammadu lẹyin nile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, ni yoo gba ipo rẹ bayii.

Oluwa rẹ ni adajọ Olukayode Ariwoola, ti ireti si wa pe wọn yoo bura fun gẹgẹ bii adele adajọ agba loni ọjọ Aje.

Niba yii na, akọwe feto iroyin fun adajọ agba to n fipo silẹ, Ahuraka Yusuf Isah, ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni adajọ agba naa ti kọwe fipo rẹ silẹ.

Bakan naa lo ni ọsan oni ọjọ Aje ni wọn yoo bura fun adajọ agba tuntun ti yoo gba ipo rẹ.

Amọ Isah salaye pe ilera adajọ agba naa ti ko gbewọn to lo mu ko fipo rẹ silẹ.