Àwọn nkán tí ẹni tó bá fẹ́ pa ẹran ileya kó gbọ́dọ̀ ṣé ní ìpalẹ̀mọ́ dé ọdún Eid-il-Adha

Afihan ẹni to mu agbo ileya lọwọ

Wakati diẹ lẹyin ti ijọba Saudi kede pe awọn ti ri oṣu oju ọrun tuntun to tọka si pe oṣu Dhul Jihha bẹrẹ, olori awọn musulumi ni Naijiria, Sultan Sokoto Muhammad Sa'ad Abubakar naa fi ikede sita.

Ni bayi ti ko wa ruju mọ ọjọ ti ọdun Eid-il Adha taa mọ si ọdun ileya yoo jẹ, nkan to ku bayi ni pe ki a maa da arawa lẹkọ nipa awọn ohun ti musulumi gbọdọ ṣe ati eleyi ti o yẹ ko yago fun bi ọdun yi ṣe n sunmọ.

Akọkọ naa, ka fi to ara wa leti pe ọjọbọ tii ṣe ọgbọn ọjọ oṣu Kẹfa ni oṣu Dhul Hijja bẹrẹ.

Eyi tunmọ si pe ni ọjọ kẹsan oṣu Keje ni ọdun ileya yoo bọ si eleyi to ṣe dede ọjọ Kẹwa ninu oṣu Dhul Hijja onka musulumi.

Pataki Oṣu Dhul Hijja

Aworan Kaaba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu ẹsin Islaamu, oṣu mejila to jẹ oṣu ojuọrun lo wa.

Ninu wọn wọn ṣa awọn oṣu kan lẹṣa yatọ si awọn to ku.

Oṣu Dhul Hijja taa n wi yi jẹ oṣu kan to ṣe pataki koda o wa lara awọn oṣu abiyi mẹrin ti awọn musulumi maa n ṣe apọnle fun.

Ninu oṣu yi ni wọn to lọ ṣe Hajj yoo maa gun oke Arafa ni Saudi ti awọn ti ko si lọ si Hajj to wa nile yoo si gba awẹ gẹgẹ bi ijọsin ti wọn.

Lọjọ keji ọjọ Arafa ni wọn maa n pa ẹran ileya ṣugbọn ki a to ṣalaye lori eleyi, o ni awọn nkankan ti eeyan ko gbọdọ ṣe to ba ni eronmgba lati pa ẹran adiya.

Aworan awọn to n ta ẹran ileya

Awọn nkan ti ẹni to ba fẹ pa ẹran Ileya ko gbọdọ ṣe

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Akọkọ ninu awọn ma ṣe fun ẹni to ba wa nile to fẹ pa ẹran ileya ni pe o gbọdọ yago fun gige eekanna tabi fifa irun ori, abẹ tabi aaye miran ni kete ti oṣu Dhul Hajj ba ti bẹrẹ.

Ohun ti eyi tunmọ si ni pe ẹni ba fẹ pa ẹran ileya ni lati ge irun rẹ ṣaaju ki oṣu yi to bẹrẹ.

Bi eeyan ko ba ni ikapa lati pa ẹran ofin yo kokan rara.

Ninu oṣu yi bakan naa, awọn onimọ ẹsin gba awọn musulumi niyanju lati ri wio pe wọn mura si awọn iṣẹ oloore bi kika al-Quran ati ṣiṣe itọrẹ lọpọ lọpọ.

Wọn tun sọ pe awọn pẹpẹnfuru mii bi ki eeyan maa gba awẹ tabi ko maa ji loru ṣe Nafila loore pupọ ninu awọn ọjọ mẹwa akọkọ ninu oṣu Dhul Hijja.

Pataki julọ, ati ẹni to fẹ pa ẹran ati ẹni ti ko lagbara lati fi ran ṣe ijọsin, wọn gba gbogbo wọn niyanju lati gba awẹ lọjọ Arafah.

Ọjọ yi ni ọjọ tawọn to wa ni Hajj yoo peju si oke Arafah lati kun fun ọpọ adura si Allah.

Bi awọn to wa ni Hajj ba ṣe n bẹ Ọlọrun, awọn onimọ ẹsin sọ pe nkan to t ni ki awọn to wa nile naa maa fi ọkan wa pẹlu wn ninu8 awẹ lọjọ naa.