Wo ẹ̀sùn mẹ́sàn án tó lè mú kí wọ́n dá èèyàn padà sílé láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tábí Amérika

Deportation: Àwọn ẹ̀sùn mẹ́sàn án tó lè mú kí wọ́n dá ọ padà sílé láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tábí Amérika rèé

Airport

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lati igba ti ijọba ilẹ Gẹẹsi ti da awọn ọmọ Naijiria kan pada sile lati orilẹ-ede naa, ọpọ eeyan lo ti n woye ohun ti wọn ṣe ni pato.

Kii ṣe igaba akọkọ ree ti ijọba ilẹ naa tabi awọn ijọba orilẹ-ede mii yoo da awọn eeyan pada silẹ wọn.

Lẹyin iroyin naa ni ijọba ilẹ Gẹẹsi kede pe awọn ti tọwọ bọwe adehun kan pẹlu ijọba Naijiria lati maa da awọn ọdaran pada si Naijiria lati orilẹ-ede ọhun.

Ẹwẹ, ọpọ eeyan lo ti kọminu lori irufẹ ẹṣẹ ti eeyan le ṣe ti yoo fi di pe wọn n da irufẹ ẹni bẹẹ pada lati awọn orilẹ-ede to ti goke agba kaakiri agbaye pada wale.

Lọpọ igba, iwa ọdaran lo maa n mu ki wọn le eeyan pada si orilẹ-ede rẹ lati ọpọ orilẹ-ede ti wọn ba rinrinajo lọ lati ṣisẹ tabi gbafẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ẹsun ti wọn le da eeyan pada fun yatọ lati orilẹ-ede kan si omiran, amọ a oo mẹnuba awọn ẹsun ti ọpọ orilẹ-ede maa n tori ẹ da eeyan pada si orilẹ-ede rẹ.

Airport

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ẹsun to le mu ki wọn le eeyan kuro nilẹ okeere, paapaa nilẹ Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi

  • Wọn le da ọ pada silẹ ti o ba lo kọja iye ọjọ ti wọn fun ọ ninu iwe irinna Visa rẹ
  • Iwa ipa ninu ile ati iwa ipa si ọmọde
  • Gbigbe eeyan wọ orilẹ-ede naa lọna aitọ
  • Kikuna lati ṣe iforukọsilẹ ati lilo ayederu iwe igbelu
  • Lilo ayederu ile igbelu gẹgẹ bii ọmọ onilu
  • Iwa igbesumọmi
  • Fifi awọn awọn ọmọde ṣiṣẹ ologun
  • Idibo lai kii ṣe ọmọ onilu
  • Ti eeyan ba ti ṣẹwọn ri nigba bii meji tabi ju bẹẹ lọ amọ ti ko sọ fun ijọba ilẹ naa

Lara awọn ẹsun wọyin le ni ọna abayọ nigba mii, amọ o da lori orilẹ-ede ti eeyan ti wu iwa ọdaran bẹẹ ati ofin to rọ mọ iwe irinna Visa ti irufẹ ẹni bẹẹ gba.

O san ki eeyan ka nipa ofin orilẹ-ede to n lọ, ko si tẹle ofin orilẹ-ede naa ju ki wọn da pada wale lọ.