Ilé ejò sún ọjọ́ tí Ekweremadu yóò ló ní àhámọ́ síwájú sí July 7

Aworan Ṣẹnẹtọ Ekweremadu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ike Ekweremadu

Igbakeji aarẹ ile aṣofin agba Naijiria nigba kan ri Ike Ekweremadu lỌjọbọ yọju siwaju adajọ ile ẹjọ kan ni London nigba keji lati jẹjọ lori ẹsun pe o gbe ọmọde wa si ilẹ Gẹẹsi lati fi ṣowo ẹya ara.

Aṣọ ti awọn eeyan maa n wọ sare ni Ekweremadu wọ to si mu bibeli lọwọ.

Ile ẹjọ fi to leti pe wọn yoo ṣẹjọ rẹ ni ile ẹjọ majistereeti Westminster ni ọjọ Keje oṣu Keje ọdun yi.

Wọn ni ilẹ okere ni o tida ẹsẹ ẹsun ti wọn fi kan an tori naa awọn ni lati gba aṣẹ lọdọ agbẹjọro agba ki wọn to le tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ rẹ.

Wọn ko mu iwe oniduro kankan wa siwaju ile ẹjọ tori naa Ekweremadu yoo si wa ni ahamọ titi di ọjọ naa.

Labẹ ofin ifi eeyan ṣowo ẹru igbalode, Modern Slavery Act 2015,wọn fi ẹsun kan Ekweremadu ati iyawo rẹ pe wn gbero lati gbe eeyan mii wa si ilẹ naa lati lo fun anfaani ara wọn.

Iyawo rẹ Beatrice yoo pada yọju si ile ẹjọ bo ba ya nitori idauro diẹ to waye nipa ọkọ to yẹ ko gbe wa lati ọgba ẹwọn si ile ẹjọ.

Ekweremadu ,ẹni ọgọta ọdun ati iyawo rẹ, ẹni ọdun marindinlọgọta ni awọn ọlọpaa mu lẹyin ti ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa UK Metropolitan Police ṣe iwadii lori wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa Met sọ ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si BBC pe''Wọn fi ẹsun igbimọran pọ lati gbe eeyan wa lati fi ṣowo ẹya ara ni pato kan Beatrice Nwanneka Ekweremadu, 55 ti wọn bi ni ọdun1966''