Dino Melaye, Smart Adeyemi àti Peter Obi sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbẹ́jọ́ Ike Ekweremadu

Digbí ni a wà lẹ́yìn Ike Ekweremadu - Dino Melaye, Smart Adeyemi àti Peter Obi

Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lẹyin ti ijọba ilẹ Gẹẹsi fi ṣikun ofin mu igbakeji Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria nigba kan ri, Ike Ekweremadu, awọn oloṣẹlu kan ti bẹrẹ si ṣatilẹyin fun.

Awọn oloṣelu naa, ninu erongba wọn sọ pe awọn ko gbagbọ pe lootọ ni agba oloṣelu naa gbiyanju lati gba ẹya ara ọdọkunrin kan lọna aitọ.

Lara awọn oloṣelu ọhun ni Dino Melaye, Smart Adeyemi ati Peter Obi.

Ninu awọn ọrọ ti awọn oloṣelu naa n fi lede lori ayelujara, wọn ni awọn duro ti Ike Ekweremadu lasiko to n koju iṣoro yii.

Smart Adeyemi

Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin, Sẹnetọ Smart Adeyemi sọ pe awọn aṣofin Naijiria ko ni kọ Ike Ekweremadu silẹ, ati pe ọpọ ninu wọn lo ti n gbiyanju lati kan sii lati igba ti ọwọ ofin ti tẹẹ nilẹ Gẹẹsi.

Adeyemi ni awọn ohun kan wa to ṣi ṣokunkun si awọn eeyan nipa ẹsun ti wọn fi kan Ekweremadu, nitori naa, ko tii yẹ ki awọn araalu kan mọ agbelebu.

O ni “Ohun to ṣẹlẹ si Ike Ekweremadu ṣeni laanu gidi gan, o si ba awa akẹgbẹ rẹ ninu jẹ ninu ile igbimọ aṣofin nitori ọkan lara wa ni.”

“Yatọ si pe o jẹ ọkan lara wa, o jẹ ẹni to ni iwa rere ti kii si ṣe ohun ti ko ba ofin mu.”

“Amọ, ko tii yẹ ki a sare maa dẹbi fun afurasi naa lai ti mọ boya o jẹbi tabi bẹẹ kọ.”

“Gbogbo awa akẹgbẹ rẹ ni imọlara ohun to n duju kọ, a si duro digbi lẹyin Ike Ekweremadu, a ko ni fi silẹ lasiko yii.”

Dino Melaye

Nigba ti Dino Melaye n fi erongba rẹ lede loju opo Facebook rẹ lori ọrọ Ike Ekweremadu, o ni afurasi ọhun ko kan dede wọ ilẹ Gẹẹsi lati ṣe ohun to ṣe lai kọkọ fi to ijọba ilẹ naa leti.

Ninu lẹta kan to fi lede loju opo Facebok rẹ, to si fi akọle kan sii lo ti sọ ọrọ naa.

Akọle to kọ sori lẹta naa ni pe “Sẹnetọ Ike Ekweremadu sọ fun ijọba ilẹ Geẹsi nipa irinajo rẹ pẹlu ọmọdekunrin ti a n sọrọ rẹ yii.”

“Digbi ni mo wa lẹyin Ike lori ọrọ yii.”

Lẹyin naa lo tun fi awọn iwe irinna ọmọdekunrin ọhun lede, to si sọ pe ọjọ ori ori ọmọdekunrin naa ju ohun ti ijọba ilẹ Gẹẹsi sọ ṣaaju lọ.

Peter Obi

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi naa ti fi ọrọ ikẹdun ranṣẹ si Ike Ekweremadu.

Nigba to n sọrọ loju opo Twitter rẹ nipa ohun ti Ekweremadu n dojukọ nilẹ Gẹẹsi, Peter Obi gbadura fun ẹbi afurasi naa, paapaa fun ilera ọmọ rẹ to n ṣaisan.

O ni “Emi atawọn ẹbi mi wa lẹyin Ekweremadu lori iṣoro to n ba finra lọwọ.”

“A darapọ mọ awọn oninu ire to n gbadura fun iwosan ọmọbinrin Ekweremadu to ṣaisan, a si ti fa wọn le Ọlọrun lọwọ ki wọn le ri idajọ ododo gba.”