Ìyanṣẹ́lódì àwọn òṣìṣẹ́ ASUU yóò dópin láìpẹ́

Aworan awon akekoo

Oríṣun àwòrán, Google

Alaga ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ASUU, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke ni awọn ko tii gba lẹta ipe fun ipade laarin awọn ati ijọba.

Osodeke sọ bẹẹ lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin BBC Pidgin sọrọ lori ibi ti ọrọ de duro lori iyanṣẹlodi ẹgbẹ oṣiṣẹ naa.

O ni awọn ko tii gburo minisita fun ọrọ iṣẹ, Chris Ngige lori ati fopin si iyanṣẹlodi ọhun.

Osodeke ni laipẹ ni iyanṣẹlodi naa yoo dopin.

O ni ijọba kọ lati san owo oṣu awọn oṣiṣẹ nitori iyanṣẹlodi, ti wọn si rope didunkoko mọ awọn yoo jẹ ki wọn pada si idi iṣẹ wọn, amọ eyi jasi pabo.

Adari ẹgbẹ ASUU naa ni ijiroro lori adehun ẹgbẹ ati ijọba ti ọdun 2009 ti gba atunto.

O ni ohun to ku ni ki ileeṣẹ ijọba ẹka eto ẹkọ gbe e lọ fun aarẹ lati buwọlu u.

Amọ ileeṣẹ ijọba ni laipẹ ni iyanṣẹlodi naa yoo dopin ti awọn akẹkọọ yoo si pada si ẹnu ẹkọ wọn.