Ìdí tí àwọn ìbejì mi, Twinz love ṣe ń rí mi mú fi ṣe “prank” wọn rèé – Ìyá Ìbejì

“A ṣe prank gbe ọkan lara wa loyun fun iya ibeji, wọn sọkun gidi gan, koda bi a ṣe pada sọ pe irọ ni, wọn ṣi balẹ sile iwosan”.
Ṣe ẹ ranti bi awọn ibeji yii ṣe ti di gbajumọ lori ayelujara bayii pẹlu orukọ wọn “Twinz Love”? Ọjọ tun ti gun ọjọ ori wọn ti awọn mejeji si ti n ṣe ọpọlọpọ nkan kun ohun ti wọn ba bẹrẹ iṣẹ adẹrinpoṣonu lori ayelujara.
iya to bi Moyinoluwa ati Doyin Oladimeji ti ba BBC Yoruba sọrọ. Lọjọ ti a kọkọ ṣe “Facebook Live pẹlu awọn ibeji naa, iya wọn ko fẹ fi oju han.
“Mi o fẹran keeyan wọ aṣọ, ko jẹun, ko maa gbe e si ori afẹfẹ fun gbogbo aye amọ, awọn ọmọ yii...”
Báwo ni àwọn ibeji ṣe n rii yin gbe mọra to bayii?

Arabinrin Adeyinka Oladimeji tun ṣalaye pe lati kekere, oun fun wọn ni aaye lati sunmọ oun daadaa.
“Mo ni aaye fun wọn lati sun mọ mi ni gbogbo ọna tori naa ẹru kii ba wọn lati sun mọ mi tabi sọ ọrọ nipa ara wọn fun mi”.
Bi awọn naa ṣe n ṣalaye bi wọn ṣe de oke ninu iṣẹ ti wọn yan. Wọn ni awọn ko kọkọ ri eeyan to fẹran nkan ti awọn fi sita amọ o pada yi biri ti “likes” n tu puupuu.
Kehinde: Lori Instagram, a kọkọ lo Moyin&Doyin amọ Instagram kọọ, mo kan ronu ni pe ṣebi ibeji ni wa a dẹ fẹran ara wa, bi Twinz Love ṣe jade niyẹn ti gbogbo eeyan fẹran ẹ.

Oríṣun àwòrán, Twinz Love
"Awa gan ò ri iṣẹ ijọba la ṣe n dín "Doughnut" tà kun ẹfẹ taa n ṣe"

Bi wọ́n ṣe jẹ́ gbajúmọ̀ tó, wọn kawe tan ni Fasiti amọ awọn mejeeji gan ko ri iṣẹ.
Taiye: Bi emi nisinyi, mo ka “History and International Relations” ni ile ẹkọ amọ, mo maa n ji lati din ipapanu Doughnut laraarọ ni.

Oríṣun àwòrán, Twinz Love
Iya wọn taa ba sọrọ naa sọ iriri rẹ nipa ere ẹfẹ kan ti wọn ti sọ fun oun pe ọkan lara wọn loyun eyi to lagbara gan.
O ni ọjọ naa dabii pe opin ti de ba gbogbo laalaa oun lori wọn. Lootọ, lọpọ igba kii tete mọ pe ere ni wọn n ṣe.
“Ti mo ba sọ fawọn eeyan pe ọpọlọpọ nkan ti wọn ṣe yii, mi o mọ nipa rẹ rara. Omii gan wọn o le fi sita tori igba mii ti mo ba ti mọ, mo ma n daa ru fun wọn gidi gan ti mo maa binu”.

















