Odindi ọdún 17 ni mo fi wá iṣẹ́ pẹ̀lú ìwé ẹ̀rí "Mass Comm", èrè tí mò ń rí nídìí wíwa Keke Maruwa
Famuyiwa Kafayat Omobolanle jẹ akẹkọgboye ninu imọ ẹkọ iroyin ti oloyinbo n pe ni Mass Communication ni ile ẹkọ giga to wa ni ile ẹkọ gbogbonṣe Moshood Abiola to wa ni Abeokuta, ipinlẹ Ogun.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pẹlu BBC Yoruba, Kafayat jẹ ko di mimọ pe oun lọ ba ara awọn adari ajọ ẹlẹyinju aanu kan loun ṣe ri ọna abayọ amọ sibẹ naa, ẹnu sisan owo Kẹkẹ naa lo ṣi wa tori o ni ilana ti wọn fi ni ki wọn maa san an diẹ diẹ.
Ki ni o n la kọja nidi iṣẹ yii?
“N1.5M ni wọ́n gbé Keke yìí fún wa, inú mi dùn pé mo ti san bíi N600K, o ṣi ku bii N700,000 o le diẹ".
Kafayat ṣalaye pe nigba ti awọn kọkọ bẹrẹ sisan rẹ, o le diẹ koda o ni ọpọlọpọ awọn tawọn jẹ obinrin lawọn ṣaarẹ ṣugbọn ti awọn bori rẹ.

O ṣalaye bi o ṣe gbo o gidi gan lati bẹrẹ si ni wa Keke amọ ti o bori rẹ to si ti n ni afojusun fun igbega lẹnu iṣẹ yii.










