Ikú tún ṣọṣẹ́! Àgbà òṣèré Yorùbá míì ti dágbére fáyé!

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Bo ṣe n tẹ wa lọwọ bayii ni pe ọkan lara awọn agba oṣere fiimu Yoruba, Olaniyi Raji ti ọpọlọpọ mọ si “Baba Atọli” ti dagbere faye.
Ọkan lara awọn oṣerebinrin to ni ajọ kan to fi n ṣetọju awọn agba oṣere lo fi ikede yii sita ni Ọjọbọ loju opo ayelujara rẹ.

Oríṣun àwòrán, Foluke Daramola
Ninu atẹjade rẹ lo ti fi fọto Baba Atoli sita pẹlu akọle to kọ pẹlu rẹ pe “Ibanujẹ lo jẹ pe a padanu Baba Atoli, ibanujẹ gbaa ni eyi”.
Awọn akẹgbẹ wọn naa ti n fi ọrọ ikẹdun sita lọlọkanojọkan lori ayelujara to fi mọ ẹbi ati ojulumọ oloogbe.
Ṣaaju iku rẹ, Baba Atoli fi ọrọ sita lori fidio kan to ti n tọrọ fun aanu ati iranlọwọ lati tọju ailera to n koju.








