Àwa ò mọ̀ nípa afurasí tí Amotekun mú nípa ìkọlù ṣọ́ọ̀ṣì nílùú Ọ̀wọ̀ - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ondo

Awn oṣiṣẹ Ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo

Oríṣun àwòrán, Ondo state government

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti tẹnumọ pe awọn ko mọ ohunkohun nipa awọn afurasi to kọlu ijọ Aguda St. Thomas nilu Ọwọ nipinlẹ Ondo, ti iroyin sọ pe wọn wa lahamọ awọn ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ naa.

Ni Ọjọbọ ni ọga agba ikọ Amọtẹkun nipinlẹ ondo kede pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi kan ti wọn wa lara awọn agbebọn to kọlu ile ijọsin kan ni ilu Ọwọ ti wọn si pa awọn olujọsin ti ko din ni ogoji nibẹ.

Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ, Akọgun Adelẹyẹ ṣalaye pe koda ọkọ ti wọn fi sa asala kuro nibi iṣẹlẹ naa lọjọ naa wa ni ikawọ awọn ni ikọ Amọtẹkun.

Amọṣa nigba ti o ba BBC News Yoruba sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, SP Ọdunlami Ibukun ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa ko mọ ohunkohun ni pa mimu ẹnikẹni tabi afurasi kankan fun ikọlu naa.

Nigba ti a tun beere boya awọn oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun ti kan si wọn lori ọrọ naa tabi fi awọn afurasi ti wọn mu naa ṣọwọ si wọn, SP Ọdunlami ni ko si ohun to jọ rara.

Amotekun kéde pé àwọn ti mú lára àwọn agbébọn tó pa olùjọ́sìn 40 nílú Owo

Diẹ lara awọn afurasi ti ikọ Amọtẹkun fi han

Ajọ alaabo Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo ti fi idi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi kan ti wọn furasi pe wọn lọwọ ninu ikọlu ati ipaniyan to waye nileejọsin ijọ Aguda kan nilu Ọwọ nipinlẹ Ondo.

Alaga ajọ alaabo Amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo, Agba Oye Adelẹyẹ Adekunle Olusanyero ṣalaye fun BBC News Yoruba pe awọn mu awọn afurasi mọkanleloaadọrin kan, ṣugbọn lara wọn lawọn afurasi to lọwọ ninu ikọlu naa wa.

Ni ọjọ karun un oṣu kẹjọ ọdun 2022 lawọn agbebọn kan kọlu ijọ Aguda St. Thomas Catholic Church nilu Owo nibi ti wọn ti pa awọn eeyan ti ko din ni ogoji ninu eyi ti ọmọde mẹrin wa.

Ni Ọjọbọ lajọ agbofinro Amọtẹkun fi oju awọn afurasi naa han fun araye ri bi o tilẹ jẹ pe ko sọ ni pato iye awọn afurasi mọkanlelaadọrin naa to lọwọ si ikọlu to waye nilu Ọwọ.

Nigba ti BBC beere lati mọ awọn ohun ti wọn ri ti wọn fi gba pe awọn eeyan naa lọwọ si ipaniyan to waye ni ilu Ọwọ, Agba Oye Adelẹyẹ Adekunle Olusanyero ṣalaye pe ọkọ ti awọn agbebọn naa fi ṣọṣẹ naa wa lagọ Amọtẹkun bayii nilu Akurẹ lẹyin ti awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun rii nibi ti awọn afurasi naa fi pamọ si ninu igbe.

Kọmanda agba fun Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Akọgun Adeleyẹ Adetunji to ṣe afihan awọn afurasi naa ni ikọ Amọtẹkun ti bẹrẹ si ni ti ori bọ gbogbo awọn igbo nla gbogbo to wa lawọn agbegbe aala ilẹ ipinlẹ Ondo pẹlawọn ipinlẹ miran lati lee ṣawari gbogbo awọn oniṣẹ ibi to wa nibẹ lẹyẹ o ṣọka.

Diẹ lara awọn afurasi ti ikọ Amọtẹkun fi han

Ẹwẹ, awọn afunrasi ọun ni ko si lara awọn ti won fi oju wọn lede toripe ẹṣẹ tiwọn yatọ si ti awọn mọkanlelaadọrin ti wọn fihan awọn akọroyin.

Adeleye ni ko sọ iye awọn ti wọn ti mu nipa akọlu naa ati ohun ti wọn mọ nipa awọn afunrasi ọun. O fikun pe iwadi kikun n lọ lori ọrọ naa ati pe wọn yoo bun awọn araalu gbọ ti akoko ọrọ ba to.

Nigba ti BBC News Yoruba beere ọrọ yii lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, alukoror ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa ni awọn ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa ati pe awọn kọ lo gbe atẹjade naa sita.