“Mo mu ìtọ̀, mo jẹ èédú àti iyẹ̀pẹ̀ nítorí àìsàn ‘Ovarian cyst’ tó kọlù mí”

Oríṣun àwòrán, EFEZINO PATRICK
Obirin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Efezino Patrick, ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri fun BBC lẹyin ti aisan “Ovarian cyst” kọlu.
Asiko ti Efezino ṣi wa ni ẹni ọdun mẹtala ni aisan naa ti bẹrẹ ko to bọ lọwọ aisan naa lẹyin ọdun mẹwaa gbako.
Yatọ si awọn ohun ti aisan naa mu ko padanu, aisan ọhun tun mu ki idaduro de ba igbesi aye rẹ.
O ni “Ọmọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mi nigba ti aisan yii bẹrẹ, bẹẹ ni mo n gbe kiri titi de ile ẹkọ girama.”
“Aisan naa mu ki ikun mi tobi, mo si n gbe ikun nla naa kiri to bẹẹ ti awọn akẹgbẹ mi nile ẹkọ maa n ṣe yẹyẹ mi nitori bi mo ṣe ri ninu ạṣọ ile ẹkọ naa.”
Efezino ṣalaye pe ṣọọṣi ni wọn ti kọkọ sọ fun oun pe awọn kan fẹ fun oun ni majele jẹ ṣaaju aisan ọhun.
O ni “Lọjọ kan bayii ni inu bẹrẹ si n dun mi, wọn gbe mi lọ sile iwosan ni Agbarho, amọ dokita sọ pe oun ko ri ohunkohun ninu mi, bẹẹ si ni inu ọhun bẹrẹ si n wu si.”
“Ko si ibi ti iya mi ko de tan, bo ṣe n lọ sile iwosan naa lo n lọ sile awọn alagbo, to fi mọ oniruru ile ijọsin.”
“Awọn kan tilẹ sọ pe ajẹ ni mi.”
“Ko si ohun ti mi o mu ki aisan naa le lọ; bi mo ṣe n mu itọ mi naa ni mo n jẹ yẹpẹ, ti mo si n jẹ eedu.”
Mo fi ile ẹkọ silẹ nitori aisan yii

Oríṣun àwòrán, EFEZINO PATRICK
Efezino ni ohun ṣi n lọ sile ẹkọ bo tilẹ jẹ pe aisan naa ko fun oun ni alaafia titi di igba ti ọga agba ile ẹkọ naa ni ki oun ma wa mọ.
Gẹgẹ bi ohun to sọ, yatọ si ile ẹkọ oun to gba idaduro, oun ko to ẹni to n jade kuro ninu ile mọ.
Efezino sọ pe bi awọn kan ṣe n pe oun ni iya ibeji ni awọn mii n pe oun ni ajẹ, bẹẹ naa ni awọn obi kan n ki awọn ọmọ wọn nilọ lati yago fun oun.
Nipa ohun ti oju rẹ ri lasiko ti aisan naa n ba finra, Efezino sọ pe oun ko gbadura ki ọta oun ko irufẹ aisan naa lailai.
Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ pe lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo, awọn dokita sọ fun Efezino pe aisan Ovarian Cyst lo kọlu, amọ o ni oun gbagbo pe iṣẹ awọn aye ni.
Lẹyinorẹyin, wọn ṣe iṣẹ abẹ oni wakati mẹrin fun Efezino lati yọ ohun to wa ninu rẹ ohun, o si ni alaafia.
Inu mi dun lẹyin iṣẹ abẹ ti mo ṣe
Efezino sọ pe inu idunu ati ayọ ni oun wa bayii lẹyin iṣẹ abẹ naa, bẹẹ lo tun ṣalaye nipa awọn ohun ti oju rẹ ri lasiko aisan rẹ.
O ni “Aisan naa lo da igbeyawo awọn obi mi ru, iya mi tun padanu owo rẹ, yatọ si awọn dukia to lu ni gbanjo loriṣiriṣi.”
“Iya mi nikan lo duro ti mi ni gbogbo igba ti mo fi n dojukọ iṣoro naa.”
“Awọn ẹgbọn mi, to fi mọ ọkọ iya mi naa ko fi mi silẹ nigba kọọkan.”
Efezino sọ pe bayii, ni ṣe lo jọ bi pe wọn gbe ẹru wuwo kan kuro lori oun.
O sọ pe “Ni bayii, mo le maa gbe igbe aye mi gẹgẹ bii awọn akẹgbẹ mi lai si wahala kankan.”
“Iyatọ to kan wa nibẹ ni apa ti aisan naa ti da simi lara, amọ ko ṣe nnkan.”
O ni oun nireti pe oun yoo ṣi pada sile ẹkọ laipẹ, amọ lọwọ yii oun ti n kọ iṣẹ awọn aṣaraloge ati ayaworan.












