Ilé ẹjọ́ dá ẹ̀wọ̀n ọdún 235 fún Olatunji Ishola lórí ẹ̀sùn jìbìtì owó lórí ayélujára ní Uyo

Adajọ́ Agatha Okeke ti ileejọ́ giga ni Uyo ni ipinle Akwa Ibom lo se idajo naa.

O ni pe ki olujejọ́ Scales Olatunji Ishola lo fi ọdun ojilenigba o din marun jura.

Olatunji ni ajo to n gbogun ti iwa ibaje EFCC mu lori esun pe o n se jibiti owo lori ayelujara to si n kowo ilu lo sile okeere lona aito.

Lati osu keje, odun 2019 ni won ti bere si igbejo Sclaes Olatunji ki Adajo Agatha to da ejo naa bayii.

Esun Onigun marundinlaadota ni won fi kan an to si ni pe oun ko jebi pelu alaye ni ibere igbejo naa.

EFCC

Oríṣun àwòrán, @EFCC

Kini Ese Scales Olatunji?

Ileejo ni pe Olatuji ati awon merin mii ni ọwọ́ tẹ̀ gẹ́gẹ́ bii afurasi pe won gbe owo to po laarin osu kinni odun 2017 si osu kewaa, odun 2018.

Won si n wa awon merin to ku ti won jo sise ibi yii.

Won ni Scales Olatunji Ishola tun kowe sile ise ti kii se ti joba kan to je ti alaanu nile okeere lati pese papa isere boolu fun awon omodebinrin ati okunrin ni Kobane.

Olatunji lo ami idanimo ara Norwey kan to n gba boolu fi ko iwe ebẹ̀ naa.

Eni yii ni aare tẹ̀lẹ̀ fun egbẹ́ awon agbaboolu nibe ti oruko re n je Per Ravn Omdal to fi n beere fun €64,000.00

Won ni won si san owo yii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Adajo Okeke ni pe Scales Olatunji jebi esun marundinlaadota naa.

Ati pe eri to daju ni ajo EFCC gbe wa.

Ileejo tun gbese le owo to gba loruko ara Norweg na.

Adajo da ewon odun meje, marun un fun ejo kefa de ejo karundinlaadota to sẹ̀.

Awon ewon re yii ni yoo maa lo wonu ara won ni ogba ẹ̀wọ̀n bere lati igba ti owo ofin ti tee.