Olùdíje SDP fún ipò gómìnà l'Ekiti, Segun Oni gba ilé ẹjọ́ lọ

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo bayii ni pe Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu SDP, Oloye Ṣẹgun Oni ti gba ile ẹjọ lọ ni irọlẹ Ọjọbọ lati fi ẹhonu rẹ han nipa esi idibo gomina ipinlẹ naa to waye lọjọ kejidinlogun oṣu keje ọdun 2022.

Ṣẹgun Oni lo ṣe ipo keji ninu esi ibo sipo gomina ni ipinlẹ Ekiti ni ọjọ kejidinlogun oṣu kẹfa ọdun 2022.
Ibo ẹgbẹrun mejilelọgọrin o le diẹ (82, 211) ni Sẹgun Oni ni, ti Oyebanji to jẹ oludije APC si ni ẹgbẹrun mẹtadinlaadọwa, (187,057) lati gbe igba oroke.
Bisi Kọlawọle ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣe ipo kẹta pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹtadinlaadọrin o le (67, 457). Ẹkunrẹrẹ iroyin n bọ laipẹ...








