'Gbogbo àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Sofiat ló ṣì wà ní àhámọ́'

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ǹjẹ́ ẹ rántí àwọn ọmọkùnrin mẹ́rin tí àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán nínú oṣù kìíní ọdún yìí fẹ́sùn wí pé wọ́n pa ọmọbìrin kan Sofiat Okeowo láti ṣe ogun owó.
Ní ìlú Abeokuta ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé níbi tí àwọn ọmọkùnrin mẹ́rin yìí ti pa Sofiat tí wọ́n sì jó orí rẹ̀ nínú ìkòkò láti ṣe ogun owó.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí ni ìròyìn gbòde wí pé ọ̀kan lára àwọn afurasí mẹ́ta tó wà ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn náà tí jáde láyé.
Èyí ló mú wa ṣe ìwádìí bóyá lóòótọ́ ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin ọ̀húnti papodà lóòótọ́.
Àmọ́ iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ìpínlẹ̀ Ogun ti jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀ náà.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ìpínlẹ̀ Ogun, Victor Oyeleke nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lórúkọ ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà, Alimi AbdulRasheed ní irọ́ tó jìnà òótọ̀ ni ìròyìn náà.
Àtẹ̀jáde náà ní àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà ní àhámọ́ àwọn fún ẹ̀sùn ìpànìyàn ló wà ní àláfíà láì ṣe àárẹ̀ débì tí wọ́n yóò papodà.
Oyeleke ní ó pọn dandan fún àwọn láti sọ àfọ̀mọ̀ ọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà nítorí gbogbo àwọn ìròyìn tó gba orí rédíò àti ayélujára.
Ẹ ó rántí wí pé àwọn mẹ́rin Waris Oladeinde, Balogun Mustakeem, Abdulgafar Lukman àti Majekodunmi Soliudeen ni ilé ẹjọ́ fi si àhámọ́ ní ọjọ́ Kẹta oṣù Kejì, ọdún yìí lórí ẹ̀sùn.
Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹta ni ilé ẹjọ́ tú Waris Oladeinde sílẹ̀ wí pé kò ní ẹjọ́ kankan láti jẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Láti ìgbà náà ló ti ku àwọn mẹ́ta nínúọgbà ẹ̀wọ̀n tí ilé ẹjọ́ fi wọ́n sí
Oyeleke wá rọ̀ àwọn akọ̀ròyìn láti máa wàdìí ìṣẹ̀lẹ̀ dáadáa kí wọ́n tó máa gbé ìròyìn sórí afẹ́fẹ́ àti ayélujára.












