BBC tú àṣírí àwọn tó ń kó ọmọdé ṣòwò ẹrú
Forced to beg: BBC tú àṣírí àwọn tó ń kó ọmọdé ṣòwò ẹrú
Ẹka iwadii ileesẹ iroyin BBC, Africa Eye, ti tu aṣiri bi awọn eeyan kan ṣe n ko awọn ọmọ alaabo ara ṣowo ẹru laarin Tanzania ati Kenya.
Gẹgẹ bii aṣiri ti BBC tu, ṣe ni wọn lọ n fi awọn ọmọ naa tọrọ bara lẹyin ti wọn ba ko wọn kuro lakata awọn obi wọn tan.
Akọroyin BBC lati Kenya, Njeri Mwangi, to ṣabẹwo si ibi ti wọn ko awọn ọmọ naa si lo nnkan bii ọdun kan lati ṣe iwadii ọhun.
O ni pupọ ninu awọn ọmọde alaabo ara to n tọrọ owo loju popo ni Kenya n i wọn fi ẹtan ko wa lati Tanzania.

Itan ọkan lara awọn ọmọ naa to ṣeni laanu ju ni ti eyii ti orukọ rẹ n jẹ Fara, ti wọn ti n fi ṣowo ẹru naa lati ibẹrẹpẹpẹ aye rẹ.
Ọmọ naa ṣalaye fun BBC pe o ti pẹ ti oun ti wa ni Kenya lati tọrọ owo, wọn ko si gba oun laaye lati ba iya oun sọrọ lati ọdun ti wọn mu oun kuro nile.
Ninu iwadii, a ri pe ni gbogbo igba ti ti Fara ba ti lọ tọrọ owo to si pada si ọdọ awọn to ko lẹru, ṣe ni wọn maa n gba owo naa lọwọ rẹ lai fun ni iye kankan, iye owo to si maa n pa lojumọ ko din ni $18.
Yatọ si Fara, awọn ọmọde mii lo tun maa n tọrọ owo lagbegbe kan naa ti Fara wa , ọkunrin ti oun funra rẹ si jẹ alaabo ara ni wọn maa n ko owo naa fun.
Ni ti bi wọn ṣe n ri awọn ọmọ naa ko lọ si Kenya lati sinru, iwadii BBC fi han pe ṣe ni wọn maa n tan awọn obi awọn ọmọ naa pẹlu ileri igbeaye to rọrun loke okun lati fi ọmọ wọn silẹ.
Ẹkunrẹrẹ bi iwadii naa ṣe lọ ati bi aṣiri awọn to n ko awọn ọmọde naa sinru ṣe tu wa ninu fidio yii.













