Ṣé lóòtọ́ọ́ ní Banji Akintoye ná N6m owó Ilana Omo Oodua lókè òkun?

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ ilana Ọmọ Oodua ti fesi lori fọnran ohun kan to gba ori ayelujara kan, eyi to n fẹsun kan adari ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye.
Ninu fọ́nrán ohun naa ni wọn ti fi ẹsun kan Akintoye pe o gba owo to le ni miliọnu mẹfa naira ni ọwọ ẹka ẹgbẹ Ilana Omo Oodua to wa ni Canada, ti ko si lo o fun ilọsiwaju ẹgbẹ.
Bakan naa ni fọnran ohun naa tun fi ẹsun kan Akintoye pe se lo n lu owo ẹgbẹ ni gbanjo.
Ninu fọnran naa ni Adeniran ati ọkan lara ọmọ ẹgbẹ naa kan to wa lorilẹede Amerika, ti n sọrọ pe igba kan wa ti Akintoye beere ẹgbẹrun meji dọla lọwọ awọn lati lọ si Brazil.

Oríṣun àwòrán, Others
"Awọn ọmọ ẹgbẹ ti inu n bi, ni awọn to n gbe iroyin ofege naa sita"
Awọn ẹsun ti wọn fi kan asaaju Alana naa, lo mu ki ẹgbẹ ọhun tete fi atẹjade kan sita nipa rẹ.
Atẹjade naa, ti ẹgbẹ Ilana Omo Oodua fi lede fawọn akọroyin ni awọn ọmọ ẹgbẹ ti inu n bi ni awọn to n gbe iroyin ofege naa sita.
Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ni ko si otitọ kankan ninu iroyin ti wọn fi lede nipa adari ẹgbẹ naa,
Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua naa ni ki awọn eniyan kẹyin si Ọjọgbọn Wale Adeniran, ti wọn fura si pe ohun rẹ lo jade ninu fọnran ohun to n ja lori ayelujara naa.
"A rọ araalu lati maṣe gba ọrọ ori ẹrọ ayelujara gbọ tori fabu laṣan ni"
Atẹjade naa sọ siwaju pe ‘’Fọnran naa ṣafihan pe Wale Adeniran n gbiyanju lati ba orukọ Banji Akintoye jẹ ni, paapaa lori ẹrọ ayelujara.
‘’Nitori naa a rọ awọn araalu lati maṣe gba ọrọ ori ẹrọ ayelujara gbọ nitori fabu ọrọ ẹyin laṣan ni, to fi mọ ahesọ.’’
‘’Awọn wọnyii fẹ da ẹgbẹ Ilana Omo oodua ru, ni wọn ṣe n sọrọ kubakugbe nipa adari ẹgbẹ naa, wọn ko ni ohun rere lati ṣe fun ẹgbẹ naa.’’
‘’Amọ a gbagbọ pe imọ wọn ko lee ṣẹ lailai, gbogbo ohun ti wọn n ṣe lati ba orukọ wa jẹ ko lee jasi rere.’’















