'Ile Ife ni àwa Ijebu ti wá ṣùgbọ́n ìtàn náà pín sí méjì'; wo ìtàn bí Ijebu ṣe ṣẹ̀ wá

Àkọlé fídíò, itan ilu Ijebu
'Ile Ife ni àwa Ijebu ti wá ṣùgbọ́n ìtàn náà pín sí méjì'; wo ìtàn bí Ijebu ṣe ṣẹ̀ wá

Oniruuru itan lo ti jade nipa ilu Ijẹbu ode ati ilẹ Ijẹbu lapaapọ.

Nigba ti BBC News Yoruba tọ awọn agba to mọ itan lọ nilẹ Ijẹbu, alaye ti wọn ṣe ni wi pe lati ibudo mẹta lawọn to tẹ Ijẹbu do ti ṣẹ wa.

Alagba Fassy Yusuf to jẹ Oloye Baagbimọ Ilẹ Ijẹbu, to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe ilu Ile Ifẹ, Wadai ati Saudi Arabia.

Oloye Fọlọrunṣhọ Kuku to jẹ Ọgbẹni Ọja ilẹ Ijẹbu, ṣalaye pe: "Ọbanta, iyẹn wa lati ilu ile Ifẹ. Ọmọ obinrin ni ṣugbọn o tan mọ Oduduwa.

Ẹ jẹ ka jọ wo fọnran yii ninu eyi ti awọn agbaagba nilẹ Ijẹbu ti sọrọ lori bi ilẹ Ijẹbu ṣe ṣẹ wa.