Ghana elections 2020 winner: Nana Akufo-Àddo àti John Dramani ló jọ ń díje lọ́là

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ keje, oṣu kejila, ọdun 2020 ni awọn eeyan orilẹ-ede Ghana maa ni anfani lati yan ẹni to wu wọn sipo aarẹ.
Awọn oludije mejila ni gbogbo awọn to n dije dupo naa bayi.
Awọn eekan meji ni ariwo pọ lori iyansipo wọn.
Nana Akufo-Addo lati ẹgbẹ oṣelu NPP ati John Mahama lati ẹgbẹ oṣelu NDC ni wọn n sọ nipa wọn ju, eyi lo si fa nkan mẹrin to ya eto idibo yii sọtọ.
- Ohun tó yẹ kẹ́ẹ mọ nípà olùdíje mèjì tó lágbára nínú ìdìbò Ghana rèé
- Omiyalé ní Ghana, èèyàn 28 dolóògbé!
- China, Nàìjíríà, kò s'áyè òwò mọ́ ní Ghana! - Ààrẹ Akufo-Addo
- Gbajabiamila balẹ̀ sí Ghana láti pẹ̀tù sááwọ̀ láàrin Nàìjíríà àti Ghana
- Ikú ni fífi oògùn 'Paracetamol' bọ ẹran tàbí se ẹ̀wà- Iléeṣẹ́ ìlera
Nkan to kọkọ ya idibo yii sọtọ nipe idije naa tun dabi atunṣe bii ti atẹyinwa ni.
Igba kẹta ree ti Nana Akufo-Addo ati John Mahama maa jọ figagbaga ninu idije dupo aarẹ Ghana.

Oríṣun àwòrán, facebook
Wo ǹkan mẹ́rin tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìdìbò aàrẹ Ghana tó máa wáyé lọ́la
Wọn kọkọ jọ pade lọdun 2012, lẹyin naa lọdun 2016 ati lọdun 2020 yii.
Eyi to jẹ igba ikẹta yii si ni igba ikéyin ti wọn a jọ pade jọ dije dupo ni igbesi aye wọn.
Eyi waye nitori pe ẹnikẹni ninu wọn to ba wọle yoo pari saa keji rẹ ni eyi to jẹ aṣegbẹyin nitrori pe ko si saa kẹta.
Ohun miran to ya idije ti ọdun yii sọtọ ni pe awọn olugbe orilẹ-ede Ghana ti dan awọn mejeeji wo ri.
Eyi difa fun pe wọn yoo yan ninu ijọba to n kọ nkan amayedẹrun ati ijọba to n ṣamojuto eto ọrọ aje.
Lọdun 2012 si 2016 ni John Mahama polongo nipa ipese ohun amayederun
O kọ awọn ile iwosan, opopona, ati awọn nkan mii ti awọn eeyan n mọ riri rẹ lẹyin to kuro nipo.
Ni ti aarẹ Akufo-Addo, ipolongo to n ṣe da lori eto ọrọ aje, eto ọgbin, ati ipese iṣẹ yatọ si ikoju ajakalẹ arun Covid 19.
Ti Ghana ba dibo fun NDC o tumọ si pe ohun amayedẹrun ni wọn yan ṣugbọn ti wọn ba dibo fun Nana akufo-Addo lẹẹkan sii, o tumọ si pe eto ọrọ aje ni wọn fẹ ko fi ẹsẹ mulẹ sii.
Bawo ni a ṣe maa mọ ẹni to ba jawe olubori ni Ghana?
Ibi mẹta gboogi ni yoo sọ ẹni to maa wọle ninu awọn oludije mejila naa.
Accra, Central ati Western ni gbogbo oju wa bayii.
Iye ibo to ba wa lati ẹkun Ashante naa yoo ṣe daadaa fun NPP nigba ti ibo to ba wa lati ekun Volta yoo ran NDC lọwọ.
Fun idi eyi, ninu idibo to m bọ ni ọla lati awọn ẹkun yii ni a o ti mọ bi ohun gbogbo yoo ṣe ri fun ẹni ti yoo gba ade aarẹ Ghana.
- Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun ti Olorì Naomi bí títí di bíi ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà?
- Ṣé ẹ rántí àkọ́lé àwọn ìwé àkàgbádùn yìí?
- Àwọn Olúkọ ìpínlẹ̀ Oyo fakọyọ lórí ètò Akọ́mọlédè àti Àṣà púpọ̀
- Látilẹ̀ ni mo ti fẹ́ràn orin ìjọ Kérúbù àmọ́ ẹlẹ́sìn mùsùlùmí àti krìstẹ́nì ni mí- Qdot
- Ọkùnrin kan "lu ìyàwó rẹ̀ pa" nítorí ó lọ síbi ayẹyẹ ìsọmọlórúkọ















