Lamidi Adedibu: Èyí ní àlàyé bí akọni olóṣèlú nílẹ̀ Ibadan ṣe sẹ̀ wá

Irú ọmọ Oluyole ni Adedibu jẹ, ìpasẹ̀ akọni náà ló ts nígbà ayé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọ́n ti sàpèjúwé Lamidi Adedibu gẹ́gẹ́ bi ojúlówó ọmọ Iba Oluyole, ọ̀kan pàtàkì lára àwọn tó jàjà òmìnira nílẹ̀ Ibadan.

Nínú ìwé ti wọ́n pe àkọle rẹ̀ ni "Adedibu the Strongman and Generalissimo of Nigeria Politics" èyí ti Hazeem Gbolarunmi àti olóyè Lekan Saka jìjọ kọ, ni ọ̀rọ̀ yìí ti jẹyọ.

Ìwé náà sọ nípa ìgbé aye gbajúgbajà olóṣèlú Ibadan náà, ti àwọn ọmọ àti olùgbé Ibadan ko le gbàgbé ipa tó kó nínú ètò òṣèlú.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọ́n ni yàtọ̀ si àwọn igbésẹ̀ akin tó gbé, àwọn ènìyàn kò le gbàgbé bi àwọn jànduku ṣe pọ̀ tó lásìkò rẹ̀ àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ míràn tó jẹyọ nílùú Ibadan àti ni ìpińlẹ̀ Oyo lápapọ̀, lasiko aye oloogbe naa.

Àkọlé fídíò, Zlatan: Ọ̀rẹ́ ni mo sìn lọ ‘studio’ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ orin lẹ́yìn tí mo kùnà ìdánwò WAEC

Ẹ̀wẹ́, òǹkòwé náà sàlàyé pé, Adedibu fi ìwà jọ akọni lójú ogún ilẹ ìbàdan kan, ti orúkọ rẹ̀ tàn ká ilé, tàn ká oko, eyiun Iba Oluyole.

Oluyole jẹ adarí àwọn ọmọ ogun Ibadan, tí ìwà adarí rẹ si jẹ èyí tí ìlú ń fẹ́.

Ilé Olukuoye ni Oluyole ti wa, láti ara ọmọba Agbonyin to jẹ ọmọ aláàfin Abiodun, ẹni tii se Alaafin to jẹ́ pé oun níkan lo bori Basorun Gaa lásìkò Oyo atijọ.

Àkọlé fídíò, Omolola Arohunmolase Welder: Mo ti fí iṣẹ́ 'Welder' gbayì láwùjọ, tó mo fi tọ́ ọmọ yanjú

Oluyole si tun jẹ ọkan lára àwọn tí wọ́n ń wò bí ẹni to gbé ilẹ̀ Ibadan ró.

Gẹ́gẹ́ bi Oluyole, ile Olupoyi ni Adedibu naa ti wa ni Oja-Oba Ibadan sùgbọ́n ó tan mọ́ Oluyole lati ilé ìyá rẹ̀.

A bí Adedibu ni ọjọ́ kẹrinlélógún, oṣù kẹwàá ọdun 1927 ni Oja -Oba Ibadan, ó jẹ́ ọkan lára to wá láti ilé tó ń joyè Olupoyi, tí a si le tọ ìràn rẹ̀ si Iba Oluyole.

Lamidi Adedibu fi ipa mánigbàgbé lélẹ̀ ní agbami òṣèlú

Aworan Obasanjo ati Adedibu

Oríṣun àwòrán, Obasanjo Foundation

Lai si ti Adedibu ẹgbẹ oṣelu PDP ki ba maa ti ni Gomina lasiko isejọba mi.

Ọrọ iranti ree ti aarẹ ana, Olusegun Obasanjo fi ṣapejuwe agba ọjẹ oloṣelu ipinlẹ Oyo nni, Lamidi Adedibu, se arise ni arika.

Obasanjo fi ọrọ yii lelẹ lasiko ifilọlẹ iwe kan ni iranti Adedibu, ti wọn pe akori rẹ ni "Adedibu The Strongman and Generallisimo of Nigerian Politics: An X-ray of the Political Life of a Colossus",

Ni gbọngan Trenchard ninu ọgba fasiti Ibadan ni aarẹ Obasanjo ti sọrọ naa, to si ni Adedibu ṣe bẹbẹ lasiko igbe aye rẹ.

Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, o ni 'Adedibu fi ipa manigbagbelelẹ lagbami oṣelu ilẹ kaarọ o jiire.

Àkọlé fídíò, Baruwa Gas Explosion: Àwọn tó forí sọta ìjàmbá iná ń bẹ ìjọba láti dìde ìrànwọ́

''Mo ranti igba ti ọrọ pa wa pọ, to sọ fun mi pe oun dije lọdun 1954 pẹlu baba ẹni to fẹ du ipo Gomina lọdun 2003. Ile iwe girama ni mo wa ni igba naa''

''Lai si ti Adedibu, oludije fun ẹgbẹ oselu PDP ko ba maa le wọle ibo lati di Gomina lọdun 2003, nigba ti mo jẹ aarẹ Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ta n wi yii, mo lọ ba Alagba Emmanuel Alayande to si sọ fun mi pe, ẹni to n du ipo Gomina ko kunju oṣunwọn''

Bo ti lẹ jẹ wipe Obasanjo ko darukọ ẹni naa, Gomina tẹlẹ ri, Rasidi Ladoja lo jẹ oludije ẹgbẹ PDP nigba naa, to si pada wọle si ipo Gomina.

Àkọlé fídíò, Ladoja

Lakotan ọrọ rẹ, Obasanjo sọ pe oun lọ si ọdọ Adedibu to si ni lootọ lọrọ ti Alayande sọ.

Obasanjo tẹsiwaju pe, oun beere pe bawo ni ẹni ti ko kunju osunwọn yoo ṣe wọle ibo Gomina.

Ni idahun si ibeere yii, Adedibu ni to ba fẹ ki awọn jẹ ko ṣeeṣe, yoo wọle ibo naa.

''Mo sọ fun Adedibu pe ko jẹ ki o ṣeeṣe, ababọ rẹ ni gbogbo wa pada ri wi pe PDP wọle Gomina''.

State of the Nation: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nìkan ni ọ̀nà abáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà- Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Obasanjo/instagram

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nìkan ni ọ̀nà abáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà- Olusegun Obasanjo

Ààrẹ àná lórílẹ̀-è[de Nàìjíríà Olusegun Aremu Obasanjo ni ipa pàtàkì ni ọ̀rọ̀ ọlórí àti àwọn adarí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni láti kó kí wọ́n tó borí ètò ààbò tó mẹ́hẹ, ètò ọrọ̀ ajé tó dojúdé àti ètò òṣèlú ti kò rọgbọ̀.

Obasanjo n sọ̀rọ̀ lásìkò àbẹ̀wò rẹ sí gómìnà ìpińlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde nílùú Ibadan, ní bi tó ti sàlàyé pé, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ará ìlú gan ṣe pàtàkì láti mójútó ìṣòrò tó wà nílẹ̀.

O ní gbogbo rògbòdìyàn tó n ṣẹlẹ̀ nílùú kìí ṣe tuntun bákan náà ni kìí ṣe ìṣòro tí kò ṣee bori, sùgbọ́n ó nílò ìfowọ́sowọ́pọ̀ àwọn ará ìlú bákan náà ni ìfarajì àwọn olórí.

"Ìsòro tó bá de ba ọmọ ènìyàn , ènìyàn náà ni yóò yanju rẹ̀" Ó yẹ ki gbogbo ènìyàn fọ́wọ́sowapọ̀, bákan náà ni ó yẹ kí àwọn olórí dìde gírí láti mú ìsopọ̀ àwọn ènìyàn wáyé.

Lásìkò àbẹwò Obasanjo si ẹbi Abiola Ajimobi, gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Oyo tó d'ológbèé lọ́jọ́sí, ni gómìnà Seyi Makinde ti gbaa ààrẹ àná lálejò.

State of the Nation: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nìkan ni ọ̀nà abáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà- Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Obasanjo/instagram

Nínú ọ̀rọ̀ Makinde ló ti sàlàyé fún ààrẹ àná pé, ipasẹ̀ rẹ̀ ni òun ń tọ ní ìpínlẹ̀ Oyo pàápàá jùló nínú isẹ́ ọgbìn.

Makinde ni, èyí ni láti mu ìdàgbàsókè bá igun mẹ́rẹ̀rin ìpińlẹ̀ Oyo àti pé, òpó mẹ́rìn ní ìpínlẹ̀ Oyo dúró lé lórí. Ètò ẹ̀kọ́, ìlera, ètò ààbò àti ìdàgbàsókè, ètò ọrọ̀ ajé.

Lórí ìpè àwọn ènìyàn pé kí ààrẹ Buhari yọ àwọn ọgagun elétò ààbò nípò, Obasanjo ni òun kọ́ ni òun yàn wọ́n sípò, nítorí náà, òun kò le pè fún ìyọ̀ nípò wọ́n.