Abiola Ajimobi: Tinubu ní àwọn ìpínlẹ̀ ló yẹ kó máa gba owó orí ọjà

Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, @AsiwajuTinubu

Laarin oniruuru wahala to n ranju mọ eto abo ni Naijiria, aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu ti pe fun agbekalẹ ọlọpaa agbegbe ati ipinlẹ.

Aṣiwaju Tinubu ni asiko ti to bayii lati gbe ọlọpaa agbegbe kalẹ gẹgẹ bi ọna ati mu ki eto abo wa fun tẹru-tọmọ laisi pe araalu n kọ iha kokanmi si abo layika ati orilẹede wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo tun pe fun mimu adinku ba agbara to wa ni ijọba apapọ, ki idagbasoke le de ba awọn ipinlẹ atijọba ibilẹ.

Florence Ajimobi n kunlẹ ki Ọọni tilu Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiolaajimobi

Oloye Tinubu yannana ọrọ yii ninu ọrọ to fi ranṣẹ sibi apero ọlọdọọdun ti wọn fi sọri oloogbe Abiọla Ajimọbi, eyi to waye nilu Ibadan.

Agba oṣelu naa ni o yẹ ki ojuṣe gbigba owo ori lori ọja (Stamp duty) ati ibudo igbafẹ (Tourism tax) jẹ ohun tawọn ijọba ipinlẹ yoo maa gba.

Lara awọn to wa nibi apero ọlọdọọdun ti Abiola Ajimobi naa ni Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ati Gomina Dapo Abiodun tipinlẹ Ogun.

Ganduje n si ọwọn iranti Abiola Ajimobi, ti Ganduje si duro ti

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiolaajimobi

Awọn yoku ni Gomina Abdulahi Ganduje ti Kano, Gomina Kayode Fayemi ti Ekiti, Gomina Rotim Akeredolu ti Ondo ati Oloye Bisi Akande.

Bakan naa ni Dokita Obafemi Hamzat, tii se igbakeji Gomina ipinlẹ Eko, Oloye Adebayo Adelabu, Ọmọwe Onikepo Akande, ati adele giwa fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Babatunde Ekanọla ko gbẹyin nibi eto idanilẹkọ naa.