Ìdí tí mo fi sá pamọ́ lẹ́yìn awuyewuye ìbò gómìnà ní Adamawa, adarí INEC Hudu Ari ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, other
Adari ajọ INEC ni ipinlẹ Adamawa ti olu ileeṣẹ ajọ naa ni ko lọ rọọkun nile, Yunusu Ari ti sọ pe oun ko kabamọ kankan pẹlu bi oun ṣe kede oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC, Aisha Binani gẹgẹ bi olubori ibo gomina ipinlẹ naa.
Ari ṣalaye ninu ifọrọwer kan pẹlu BBC pe gbogbo ofin to yẹ loun tẹle ki oun to kede oludije APC naa gẹgẹ bi olubori.
Kikede ti Ari kede Binani gẹgẹbi olubori ibo gomina nipinlẹ Adamawa da oniruuru awuyewuye ati wahala silẹ pẹlu bi o ti jẹ wi pe wọn ko tii ṣe akojọpọ ibo tan nigba naa.
Igbesẹ yii lo mu ki olu ileeṣẹ ajọ INEC o paṣẹ fun Ari pe ko lọ rọkun nile, ti aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu si tun paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa o ṣe iwadii adari ajọ INEC ni ipinlẹ Adamawa ọhun ati gbogbo awọn adari ileeṣẹ alaabo gbogbo to wa pẹlu rẹ lasiko ti o fi ṣe ikede naa.
Ẹnikẹni ko fun mi ni N2biliọnu lati kede Binani
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Ari sọ pe, “Mo sọ fun yin pe mi o kabamọ igbesẹ mi naa, niwn igba to jẹ wi pe eeyan kii kabamọ ṣiṣe ohun gbogbo ni ibamu pẹlu ilana ofin.”
Bakan naa ni Amofin Hudu Ari tun ṣalaye pe ko si igba kankan ti oun gba owo riba biliọnu meji naira lọwọ ẹnikẹni lati le kede Sẹnetọ Aishatu Binani gẹgẹbi olubori ibo naa.
Binani ni oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo gomina lasiko ibo apapọ ọdun yii lorilẹede Naijiria.
Binani ati gomina Ahmadu Umaru Fintiri ni wọn jijọ ta kangbọn fun ipo gomina ipinlẹ naa ki INEC to kede Fintiri gẹgẹ bi olubori lẹyin ti wọn pari akojọpọ ibo gomina naa.
Amofin Hudu Yunusa ni ofin eto idibo ni Naijiria fun oun laṣẹ lati kede esi ibo.














