King Charles III: Kí ni Ọba Charles sọ nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tó bá ìlú sọ?

Ọba Charles Kẹta ti ba àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè UK sọ́rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́.
Ní ààfin Buckingham ní ìrọ́lẹ́ ọjọ́ Ẹtì ló ti sọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn ikú ìyá rẹ̀, Ọbabìnrin Elizabeth Kẹta tó dágbére fáyé lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹsàn-án.
Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yìí ló wà lára ayẹyẹ ìsìn tí wọ́n là kalẹ̀ láti fi ṣẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Ọbabìnrin náà èyí tó wáyé ní ilé ìjọsìn Cathedral ìlú London níbi àwọn olóṣèlú bíi Olóòtú ilẹ̀ UK, Liz Truss, olórí ẹgbẹ́ alátakò, Sir Keir Starmer àti Mayor ìlú London, Sadiq Khan péjú sí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Britain náà ló wà níbi ayẹyẹ shún.
Ṣaájú ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì ni àwọn èrò ti péjú pésẹ̀ síwájú ààfin Buckingham láti gbé òdòdó kalẹ̀ láti bu ọlá fún Ọbabìnrin tó dolóògbé lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún.
Lára àwọn ohun tí Ọba Charles sọ nípa ìyá rẹ̀ rèé
1. Ó yin ìyá rẹ̀, Ọbabìnrin tó wàjà lákin
Ọba Charles bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa gbígbé oríyìn fún Ọbabìnrin tó gbésẹ̀ tí ń ṣe ìyá rẹ̀.
Ó jùwé Ọbabìnrin Elizabeth gẹ́gẹ́ bí ohun ìwúrí àti àwòkọ́ṣe fún òun àti gbogbo ẹbí.
Ọba Charles ni gbogbo iwọ̀ tó yẹ kí ọmọ ṣe fún ni àwọn jẹ Ọbabìnrin náà fún ìfẹ́, ẹ̀kọ́, ìtọ́sọ́nà àti àwòkọ́ṣe tó jẹ́ fún àwọn nígbà tó wà láyé.
Bákan náà ló ní ó gbé ìgbé ayé tó dára tá àwọn sì ń ṣe àfẹ́kù rẹ̀ giidi báyìí.
2. Ó sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀ èdè UK àti Commonwealth

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọba Charles kò sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀dùn ọkàn tí àwọn ìdílé rẹ̀ ń bá fínra lórí ìpapòdà Ọbabìnrin Elizabeth lásán, ó tún sọ̀rọ̀ lórí tí yóò ní lórí orílẹ̀ UK àti àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn.
"Yàtọ̀ sí ẹ̀dùn ọkàn tí àwa ẹbí Ọbabìnrin ń kojú lọ́wọ́lọ́wọ́, a kẹ́dùn pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè United Kingdom, àwọn orílẹ̀ èdè tí Ọbabìnrin ń ṣe olórí fún ní àjọ Commonwealth àti káàkiri àgbáyé, pẹ̀lú ìmọrírì àádọ́rin ọdún tí ìyá mi fi sin àwọn orílẹ̀ èdè tó pọ̀."
Ó ní gbogbo iṣẹ́ ìsìn tí ìyá ṣe sin ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ni òun mọ̀ wí pé ìpapòdà rẹ̀ yóò mú ẹ̀dùn ọkàn bá tí òun sì mọ̀ nípa òun tí àwọn orílẹ̀ èdè náà ń kojú.
3. Ó sọ̀rọ̀ nípa ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba

Oríṣun àwòrán, PA Media
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Ọba Charles mẹ́nuba àwọn iṣẹ́ tí yóò máa ṣe lọ́wọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí Ọba tuntun.
Ó ní gbogbo iṣẹ́ Ọba ń ṣe kí òun tó gorí ìtẹ́ kò ní yípadà àti ìbáṣepọ̀ òun sí ilé ìjọsìn ilẹ̀ England - ilẹ̀ ìjọsìn tí ìgbàgbọ́ òun rọ̀ mọ́ láti ìgbà èwe.
Ọba Charles fi kun pé nínú ìgbàgbọ́ náà ni òun yóò ti máa ṣiṣẹ́ sin àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìbọ̀wọ̀ fún àṣà àti ìṣẹ̀ṣe tí òun yóò sì gbájúmọ́ mímú ìtàn àti ètò ìṣèjọba ilẹ̀ wọn dúró ṣinṣin.
"Pẹ̀lú bí Ọbabìnrin fúnra rẹ̀ ṣe fi ara rẹ̀ jìn sí àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ni èmi náà yóò ṣe fún gbogbo ọjọ́ tí Ọlọ́run bá mi láti túnbọ̀ lò lákè eèpẹ̀ láti mú àsíá orílẹ̀ èdè wà dúró nínú ọkàn mi."
Ó ní gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè United Kingdom nílé àti lẹ́yìn odi, láì fi ti ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn ṣe ni òun jẹ́jẹ̀ẹ́ láti sìn tọkàntọkàn pẹ̀lú ìfẹ́, ọ̀wọ̀ àti ìfarajìn títí ayé òun.

Oríṣun àwòrán, Reuters
4. Ó sọ̀rọ̀ nípa ìdílé rẹ̀
Bákan náà ni Ọba Charles ipò tí àwọn ènìyàn nínú ìdílé rẹ̀ yóò máa gúnlè báyìí.
Ó ní ìyàwó òun Camilla ni Olorì tí àkọ́bí ọmọ rẹ̀, William yóò sì di Ọmọọba Wales.
"Gẹ́gẹ́ bí àrẹ̀mọ mi, William ni yóò gba ipò oyè Scottish, èyí tó ni ìtumọ̀ sí mi púpọ̀."
"Òun ni yóò di Duke Cornwall tí yóò sì máa ṣe gbogbo iṣẹ́ tó rọ̀ mọ́ Duchy Cornwall èyí tí mo ti ń ṣe fún àádọ́ta ọdún.
"Lónìí, inú mi dùn láti fi ṣe Ọmọọba tí yóò máa mójútó Wales, Tywysog Cyru, orílẹ̀ èdè ti mo fi gbogbo ọ̀pọ̀ ayé mi farajìn fún."
Bẹ́ẹ̀ náà ló sọ̀rọ̀ nípa ọmọ rẹ̀ Harry.
Ó ní òun kpo gbàgbé láti nọwọ́ ìfẹ́ sí òun àti ìyàwó rẹ̀, Meghan ní ilẹ̀ òkèrè tí wọ́n wà, níbi tí wọ́n ti ń ṣètò ìgbésí ayé wọn.

Oríṣun àwòrán, PA Media
5. Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tó múnilọ́kàn
Ọba Charles parí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú dídúpẹ́ lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ fún gbogbo ipa tó sà nígbà ayé rẹ̀.
"Sí ìwọ ìyá mi abiyamọ tòótọ́, bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò tuntun láti lọ darapọ̀ mọ́ bàbá mi, mó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ."
"O ṣeun fún gbogbo ìfẹ́ àti ìfarajìn sí ìdílé yìí àti sí ìdílé gbogbo àwọn ìlú àti orílẹ̀ èdè to sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún yìí."
"Kí àwọn áńgẹ́lì gbé ọ lọ síbi ìsinmi."

Atupalẹ iroyin lati ọwọ akọroyin ile ijọba, Sean Coughlan
Eyi jẹ ọrọ akọsọ ti Ọba Charles yoo sọ, o kun fun ọrọ itara ti ko se fi pamọ nipa ẹbi rẹ lasiko ọfọ yii.
Lara rẹ ni akọle iroyin to ni Ọmọọba William ati Kate yoo di Ọmọọba ati Ọmọọbabinrin Wales, to si fa akoso le iran to n bọ lọwọ.
Boya nitori pe o sọrọ iyi imọyi pẹlu itara fawọn obinrin meji to se koko ninu aye rẹ, iya rẹ ati Ayaba Camilla, tii se aya rẹ tootọ.
O tun sọrọ nipa "íbanujẹ nla" to ni nipa bo se padanu iya rẹ, ẹni to gbe "igbe aye daradara", ati iwa "ifiraẹnijin fun ojuse" rẹ̀, to si gbajumọ isẹ isin to n se lati ọdunmọdun pẹlu ayipada alagbara to ba awujọ
Ọba tuntun tun kan saara si "Idurosinsin ifọkansin" Ayaba tuntun, aya rẹ Camilla, to si se afihan ojuse pataki ti ko se e dunadura eyi ti yoo se ninu aye rẹ.
Bakan naa lo tun se afihan ifẹ si "Harry ati Megan bi wọn se n tẹsiwaju lati gbe aye wọn ro loke okun."
Isẹ pataki mii to tun fi ransẹ ni pe Charles de lati wa mu ayipada wa, itẹ ọba si jẹ ojuse isẹ ayeraye fun, "ni iwọn akoko to ku ti Ọlọrun ba fun mi."
Amọ ohun ọrọ akọsọ rẹ naa safihan isẹ pataki, ti ko lọwọ ohun igberaga ninu, to si n seleri lati sisẹ sin dipo ko se akoso. O tun da lori meji lara awọn ohun to ni itara le lori, eyiun Shakespeare ati ẹsin.
Bi o tilẹ jẹ pe ko si ohun to sadede waye ninu aye ọba naa ati ọrọ to jade lati aafin Buckingham, tori on ni ami idamọ tiẹ.
Ba naa sọrọ jade latinu yara ti iya rẹ maa ti n fi ọrọ sita lasiko ọdun keresimesi ati niwaju awọn oorun didun to wa fun iranti.
Ni isalẹ ike ti wọn fi awọn ohun didun naa si ni aja mta duro si.
















