Èyí ni ìdí tí èsì àyẹ̀wò ikú tó pa Mohbad kò ṣe tíì jáde – Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Eko

CP Adegoke

tilẹ jẹ pe oṣu kẹrin ree ti Ileri Oluwa Alọba (Mohbad) ti jade laye, ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti fidi ẹ mulẹ, pe esi ayẹwo iku to pa a ko ti i jade.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Mustapha Adegoke Fayọde, ṣalaye pe esi ayẹwo naa ko jade nitori eyi to ni i ṣe pẹlu awọn kẹmika ti ara ko fẹ (Toxicological result) ko ti i delẹ rara.

Fayọde sọ pe esi nipa awọn kẹmika to wa lara oku naa ti ko ti i jade, ni ko jẹ ki eyi tawọn eeyan n reti pẹlu bọ sigboro aye.

Ọga ọlọpaa Fayọde ṣalaye yii lasiko to n tọka aṣeyọri rẹ laarin oṣu kejila ọdun to kọja, si oṣu akọkọ ninu ọdun 2024 yii.

O lawọn ko si le gbe ohun tawọn ko ti i ri gba jade.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu kẹsan-an ọdun 2023 ni Mohbad jade laye.

Iku ojiji to pa a naa ru ọpọ eeyan loju lo fi dohun ti gbogbo aye n da si.

Paapaa bi wọn ṣe tun sare sin oku naa lọjọ keji lai gbe awọn igbesẹ to yẹ.

Wọn pada hu oku Mohbad lati ṣayẹwo ohun to pa a, ọpọ eeyan lo si n reti esi lati ọdun to kọja ti wọn ti wa lẹnu rẹ.

Ṣugbọn ọga ọlọpaa Eko ti ni ko ti i jade rara ni.