Gomina Adeleke yọ ọba mẹta nipo nipinlẹ Ọṣun

Gomina ipinlẹ Ọṣun, ọmọọba Ademọla Adeleke, ti yọ awọn ọba mẹta to ti kọkọ fofin de nipo patapata bayii gẹgẹ bi ọba nipinlẹ Ọṣun.
Awọn ọba mẹta naa ni Ọwa tiluu Igbajọ, Ọba Adegboyega Famọdun, Aare ti ilu Iree; Ọba Ademọla Pọnle ati Akirun tilu Ikirun, Ọba Yinusa Akadiri.
Ninu iwe ofin mẹfa to de awọn ọba naa ti Gomina Adeleke fi sita l’Ọjọbọ, ọjọ kejidinlogun oṣu kin-in-ni ọdun 2024, ni wọn ti kede pe iyansipo awọn ọba mẹta naa ko tẹle ofin.
Iwe ofin naa tẹsiwaju pe gomina Ọṣun tẹlẹ, Gboyega Oyetọla lo yan awọn ọba yii nigba ti iṣakoso rẹ ti n kasẹ nilẹ.
Igbimọ kan ti Adeleke gbe kalẹ lati wadii Akire, Aree ati Ọwa Igbajọ, ti Bunmi Jẹnyọ jẹ Alaga rẹ lo gbe abọ iwadii naa jade wayi.
Wọn ni awọn ọba mẹta naa ko yẹ nipo mọ, ati pe aaye wọn ti ṣofo fẹlomi-in lati gun ori itẹ.
‘Gbogbo igbesẹ lati da awọn ọba yii pada sori itẹ la fagile’

Oríṣun àwòrán, others
Gẹgẹ bi iwe ofin ti gomina gbe jade naa ṣe ṣalaye, gbogbo igbẹsẹ ti wọn ti gbe sẹyin lati da awọn ọba yii pada sori itẹ ni ijọba ti fagile.
Eto lati yan Aree ati Ọwa Igbajọ tuntun ni ko bẹrẹ lọwọ kan.
Wọn fi kun un pe kawọn oloye ti wọn gbẹjọ lọ si kootu nitori Aree lọọ jawọ ninu ẹjọ naa, ki eto le bẹrẹ nilana ọtun fun ọba tuntun.
Bẹẹ naa lo ri fun Ọwa Igbajọ, gẹgẹ bi iwe gomina ṣe wi.
Ni ti Akirun, gomina sọ pe ipo ọba naa ṣi silẹ titi digba ti idajọ ile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun ba jade lori rẹ
Bakan naa ni gomina kilọ fawọn ọba yooku ti awuyewuye n waye lori ipo wọn lati tẹle ofin.
‘Ofin ti ko lẹsẹ nilẹ ni’jọba Ọṣun gbe jade, wọn tẹ kootu loju mọlẹ ni’’

Lati tako awọn ofin Gomina Adeleke, awọn ọmọ oye lati Iree ti koro oju si aṣẹ gomina lori ipo Aree. Wọn ni ofin ti ko rẹsẹ mulẹ ni Adeleke ṣe.
Nigba to n sọrọ, Akowe awọn ọmọ oye n’Iree, Gbenga Ọlatunji, sọ pe kawọn eeyan Iree ṣe suuru lori ofin naa, ago awọn ni yoo de adiẹ Ademọla gbẹyin.
Ọlatunji sọ pe gomina Adeleke n tẹ oju ofin mọlẹ, pẹlu bo ṣe gbe ofin tiẹ jade lori ọrọ to wa ni kootu.
O ni kootu si ti gbe ẹjọ ti wọn fẹẹ da sibi ti wọn yoo ti he e pada basiko ba to.
‘’Ti ko ba jẹ pe awọn oṣiṣẹ ile-ẹjọ daṣẹ silẹ ni, kootu ko ba ti dajọ yẹn lọjọ kẹrinla oṣu kejila ọdun 2023.
‘’Awa ko gba iwe ofin Adeleke yii wọle, a nigbagbọ ninu ofin ile-ẹjọ ni.
‘’A mọ pe otitọ ni yoo leke gbogbo irọ wọnyi, ṣugbọn a rọ awọn eeyan wa, paapaa awọn ọmọ ile oye lati ṣe suuru lasiko yii na, ki wọn si tẹle ohun tofin sọ.
‘Gomina Adeleke fi aimọkan rẹ nipa ofin han ni, Ọsun naa lẹ ti le riru eyi’
Ọmọọba Adebayọ Adeleke, kọmiṣanna tẹlẹ fọrọ oye jijẹ l’Ọṣun, ṣapejuwe Gomina Adeleke bii ẹni ti ko mọ ofin rara.
O ni gomina fi eyi han nipa ṣiṣe ofin ara rẹ lori ẹjọ to wa ni kootu.
Ọmọoba Adebayọ to wa lati idile ọmọ oye Laaroye, sọ pe, ‘’to ba jẹ pe Gomina Adeleke rẹni gba a nimọran gidi ni, yoo mọ pe titẹ kootu loju mọlẹ ni ofin to ṣe yii. Ko si le yọri sibi ire fun un.
’’Fifi ẹtọ ile-ẹjọ dun un ni, ipinlẹ Ọṣun nikan naa lẹ ti le riru ẹ.’
O ni gomina fẹẹ dajọ ara ẹ, ko si kọ nipa ofin.
O fi kun un pe b’Ademọla ba fẹe ṣise adajọ, ko ba ti lọọ kẹkọọ nipa ofin latilẹ.














