Igbajo Osun King dead: Lẹ́yìn ìpapòdà Owa Igbajo, Ọba Fashare, àwọn afọbajẹ bẹ̀rẹ̀ ètùtù

Owa ilu Igbajọ, Ọba Fashare

Oríṣun àwòrán, Gbagede.com

Awọn igbimọ afọbajẹ ilu Igbajọ ni awọn ti bẹrẹ etutu ipapoda kabiyesi Ọwa ilu Igbajọ, Ọba Olufẹmi Fashade to waja.

Nibi ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin to waye lj Aje, Oloye Adegboyega Awomọnlo to jẹ Aṣiwaju ilu Igbajọ ṣalaye pe wọn ti fi ọrọ naa to ijọba ipinlẹ Ọṣun leti pe Ọwa ti waja.

O fi kun un pe awọn etutu ati eto gbogbo to yẹ ti bẹrẹ. Bẹẹ si ni gbogbo awọn alẹnulọrọ nipa oyejijẹ ni ilu Igbajọ naa ti gbọ sii.

Ni ọgbọn ọdun sẹyin ni Ọba Fashade gun ori itẹ.

Èèkàn Ọbalayé kan ti wàjà ní ìpínlẹ Ọ̀ṣun!

Iroyin kaakiri n sọ pe, kabiyesi Ọbalaye ilu Igbajọ, Ọwa Ilu Igbajọ Ọba Olufẹmi Adeniyi Fashade ti waja.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ, Ọwa ilu Igbajọ waja lẹyin aarẹ ranpẹ to ṣe e.

Ni ọdun 1990, tii ṣe ọgbọn ọdun sẹyin ni Ọba Olufẹmi Fashade gun ori itẹ gẹgẹ bi Ọwa ti ilu Igbajọ ki o to jade laye.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn igbimọ afọbajẹ ni ilu Igbajọ ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii, igbagbọ ọpọ ọmọ ilu naa ni pe o di igba ti wọn ba ti pari gbogbo etutu ti wọn ba fẹ ṣe.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹni ọdun mẹtalelọgọrin ni Kabiyesi Ọwa ilu Igbajọ ki o to darapọ mọ awọn alalẹ.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ wa fun yin nipa iroyin yii bo ba ṣe n jade.