Ta ni ọ̀rẹ́bìnrin tí akọrin ẹ̀mí Moses Bliss dẹnu ìfẹ́ kọ tó mi orí ayélujára tìtì?

Oríṣun àwòrán, mosesbliss/Instagram
Yoruba bọ, wọn ni ọrọ ifẹ bi adanwo ni.
Bayii ni ọrọ ri gan an pẹlu gbajugbaja akọrin ẹmi, Moses Enang ti ọpọ mọ si Moses Bliss lẹyin ti o dẹnu ifẹ ko ọrẹbinrin rẹ, Marie Wiseborn.
Bliss ẹni ọdun mejidinlọgbọn ya ọpọ awọn ololufẹ rẹ lẹnu nigba to pin awọn fọto bi o ti fun ọrẹbinrin rẹ ni oruka loju opo Instagram rẹ lẹyin to dẹnu ifẹ kọ ọ.
Lọjọ Ẹti ni ilumọọka akọrin ẹmi ọhun fun Marie to jẹ ọmọbibi orilẹede Ghana ni oruka.
Lẹyin ti o fun un ni oruka tan ni Bliss jẹ ki gbogbo eeyan mọ afẹsọna rẹ pẹlu awọn ati fọta awọn mejeeji to fi lede lori oju opo Instagram rẹ bakan naa.
Lati igba ti Bliss ti pin fọto bi o ti dẹnu ifẹ kọ afẹsọna rẹ yi lawọn eeyan ti n beere iru eeyan ti Marie jẹ gan an.
Ọpọ eeyan ni ko mo ohun kohun nipa Marie ki Bliss to pin fọto bi o ṣe dẹnu kọ ọ lori ayelujara.
Bliss sọ loju opo Instagram pe ''mo dupẹ lọwọ rẹ Marie Wiseborn wi pe o gba lati jẹ afẹsọna mi.
Mo ti ri ojurere gba lati ọdọ Oluwa.''

Oríṣun àwòrán, mosesbliss/Instagram
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ta ni Marie Wiseborn afẹsọna akọrin ẹmi Moses Bliss?

Oríṣun àwòrán, mosesbliss/Instagram
Ọpọ eeyan lo ti mọ ọdọbinrin Wiseborn gẹgẹ bi afẹsọna akọrim ẹmi, Bliss bayii.
Amọ, ọmọbinrin ju wi pe o jẹ afẹsọna olohun aro akọrin ẹmi nikan lọ.
Iwadii fihan pe Marie jẹ amofin, oniwaasu, o si tun jẹ akọrin bakan naa.
Ohun ti ọpọ eeyan tun n sọ nipa rẹ ni pe imura diẹ naa ni imura Marie bo tilẹ jẹ pe arẹwa obinrin ni i ṣe.
Ile ẹkọ giga fasiti ilu London ni Marie ti kẹkọọ gboye amofin.
Ni oṣu Keje ọdun 2022, Marie ka ọrọ apilẹkọ ni fasiti Surrey lorilẹede England bakan naa.
Ọpọ awọn akẹkọọ fasiti lo wa nikalẹ nigba to ka ọrọ apilẹkọ rẹ ọhun.
Koda, aṣọ ibilẹ orilẹede Ghana gan an ni Marie wọ nibi eto naa.
Bo tilẹ jẹ ọmọbibi orilẹede Ghana ni Marie i ṣe, ilẹ Yuroopu ni o fi ṣe ibugbe nibi ti lọ si ile ẹkọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2












