Kí ni ìdí tí àwọn aráàlú ṣe máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ́ ilé ẹjọ́ ní Afrika?

Oríṣun àwòrán, getty images
Ọrọ nipa ile ẹjọ, paapaa awọn ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi ibo jẹ eyii ti awọn araalu maa n jẹ lẹnu pupọ ni Afrika.
Lorilẹ-ede DR Congo, ile ẹjọ sọ pe Felix Tshisekedi ni awọn araalu dibo yan lẹẹkeji sipo Aarẹ, to si da ẹjọ awọn alatakjo meji nu.
Ni Senegal, gbogbo araalu lo n fi oju wọn si ara ile ẹjọ logunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2024 yii lori idajọ ti yoo ṣe lẹyin eto idibo to waye lọjọ kẹẹdọgbọn, ọdun to kọja.
Ni Naijiria, ọpọ araalu lo ni awọn ko faramọ idajọ to sọ pe Aarẹ Bola Tinubu lawọn eeyan dibo yan sipo Aarẹ ninu eto idibo to waye lọdun 2023.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ọpọ ọmọ Naijiria lo ṣi n sọ pe Aarẹ Bola Tinubu kọ ni Aarẹ awọn lẹyin ti wọn ni ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ati ile ẹjọ ja awọn lole, to si gbe ẹtọ awọn fun ẹlomiran.
Ni DR Congo, awọn fẹsun kan ile ẹjọ pe o buwọlu eto idibo to ni ọpọ magomago ninu.
Ki ni iyatọ to wa laarin igbimọ idajọ ati ile ẹjọ?
Ọjọgbọn nipa eto ofin ni fasiti Abomey Calavi, bi Benin Republic, Ibrahim David Salami, sọ pe ko fẹẹ si iyatọ kankan ninu mejeji.
Salmami sọ pe ile ẹjọ jẹ ẹka ijọba olominira to n ri si ọrọ ofin, to si n ri daju pe awọn araalu tẹle ofin naa.
O fi kun pe igbimọ idajọ lo n ri si awuyewuye eto idibo, ojuṣe rẹ si ni lati ri daju pe awọn eeyan bọwọ fun ofin ati ẹtọ ẹlomiran.
Njẹ o yẹ ki ijọba pa ilana to fi n yan awọb adajọ da?
Ọjọgbọn nipa imọ ofin ni fasiti Bandoudou, Mukadi Boni jr sọ pe ko yẹ ko jẹ Aarẹ ni yoo maa yan awọn adajọ.
Gẹgẹ bii ero rẹ, ti Aarẹ ba n tẹsiwaju lati maa yan awọn adajọ, yoo ṣoro fun awọn adajọ ọhun lati kọ ọrọ si Aarẹ lẹnu.
O ni yoo tun rọrun fun Aarẹ to yan irufẹ adajọ bẹẹ lati maa lọwọ ninu idajọ ti irufẹ adajọ ọhun yoo gbe kalẹ.














