Wo bí ìgbẹ́jọ́ Saheed Shittu, tí àwọn Alfa fi ẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́ kàn ṣe lọ ní Ilorin

Aworan Saheed Shittu

Oríṣun àwòrán, Save your Soul TV

Ile ẹjọ Upper Area ti o kalẹ si ilu Ilọrin ni ipinlẹ Kwara ti pasẹ fun ajọ ọlọpaa lati nawọ gan gbajugbaja ẹlẹsin Islam kan, iyẹn Alfa Saheed Shittu.

Alfa Shittu ni o n jẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti ẹgbẹ Association of Proud Sons and Daughters of Ilorin (Ogo Ilorin) fi kan an.

Ile ẹjọ gbe asẹ yi kalẹ lonii ọjọ kẹrinla osu keji ọdun 2024, latari ohun ti ile ẹjọ sọ pe olujẹjọ naa tapa sofin, lẹyin ti ko si farahan nile ẹjọ lati dahun si ẹsun ti wọn fi kan an.

Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ ti gbee kalẹ, olujẹjọ ọhun jẹ ilumọọka ọdaju eeyan lori ayelujara ti o si n lo "Save Your Soul TV" ati "Saheed Shittu" bi orukọ rẹ lori Facebook.

Iwe ipẹjọ naa tun fi idi rẹ mulẹ pe, Shittu ti ba awọn eeyan jankan jankan ninu ẹsin Islam niluu Ilorin ati awọn ilu mii lorukọ jẹ.

Awọn wọnyi ni, Sheikh Labeeb Adam Al ILory, Sheikh Sulaiman Faruq Onikijipa (Grand Mufti ilu Ilọrin) Sheikh Muhideen Salman (Chief Imam iluu Offa) Sheikh Amahullah Folorunsho Fagba, Sheikh Adam Abdullah Al ILory, Sheikh Kamaldeen Al Adaby ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iwe naa salaye pe olujẹjọ yii tun tabuku Alh. Adio Muritada Baban Bariga ti o jẹ Arẹ ẹgbẹ Ogo Ilorin nipa pi pee ni awọn orukọ alufansi ni inu fidio rẹ lori ayelujara, ti o tabuku rẹ lawujọ.

O salaye pe ẹgbẹ naa setan lati pese ati ṣafihan awọn ẹri fun ẹsẹ ti olujẹjọ naa ṣẹ fun ile ẹjọ lati se ẹjọ naa.

Bi Shittu ko ṣe farahan nile ẹjọ, lawọn lọya rẹ naa ko yọju lati salaye ohun ti o sokunfa aiyọju rẹ.

Eyi lo fa ti adajọ agba, Sunday Adeniyi fi pasẹ fun ajọ ọlọpa lati nawọ gan an fun ti tapa sofin ile ẹjọ.

O wa sun igbẹjọ si ọjọ kẹfa, osu kẹta ọdun yii fun itẹsiwaju ẹjọ naa.

Ẹwẹ, alukoro ẹgbẹ Ogo Ilorin lẹnu wo, iyẹn Alfa Aduagba Yusuf Lawal ti gbogbo eeyan mo si Sheikh Sakama ṣalaye pe awọn o fi ọrọ ẹṣin ṣe, sugbọn awọn fẹ dẹkun iwa ibajẹ lori ayelujara.

O ni pataki ẹgbẹ awọn ni lati gbogun ti ọta ita ati ọta inu ẹṣin ti wọn n ba ẹṣin jẹ

Lẹ́yìn Tani Olohun, gbajúmọ̀ Alfa tún wọ gàù ẹgbẹ́ Ogo Ilorin fún ẹ̀sùn ìbanilórúkọ́jẹ́

Sheikh Saheed Shittu

Oríṣun àwòrán, Save your Soul TV

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọ̀rọ̀ tún ti ń bá ọ̀rọ̀ bọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ Ogo Ilorin ìyẹn Association of Proud Sons and Daughters of Ilorin lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́.

Lọ́tẹ̀ yìí gbajúmọ̀ Alfa kan tó máa ń sọ̀rọ̀ lórí ayélujára Facebook, Save Your Soul, Sheikh Saheed Shittu ni wọ́n ń wọ lọ sílé ẹjọ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Kejì ọdún 2024.

Ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí Alfa náà lọ́rùn ni pé òun ló pilẹ̀ bí àwọn èèyàn ṣe máa ń lọ sórí afẹ́fẹ́ láti bá àwọn Alfa, pàápàá àwọn Alfa ìlú Ilorin lórúkọ jẹ́.

Ní báyìí, ati wà ní ilé ẹjọ́ Upper Area Court Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara, tó fi ibùjókòó sí Ilorin láti mọ bí ìgbẹ́jọ́ náà yóò ṣe lọ.

Àwọn agbẹjọ́rò Saheed Sittu àtàwọn tí wọ́n fẹ̀sùn kan Saheed Shittu ti wà nílé ẹjọ́ lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ àmọ́ olùjẹ́jọ́ fúnra rẹ̀ kò ì tíì dé sílé ẹjọ́.

Tí ẹ ò bá gbàgbé àwọn ẹgbẹ́ yìí ló kọ́kọ́ fi òfin gbé gbajúmọ̀ oníṣèṣe, Abdulazeez Adegbola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Tani Olohun fún ẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́ tó sì lò tó oṣù mẹ́ta ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n.

Lẹ́yìn ò rẹyìn ni wọ́n padà parí aáwọ̀ náà nígbà tí wọ́n ní kó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn tí ó bà lórúkọ jẹ́ lórí ìwé ìròyìn àti lórí ẹ̀rọ ayélujára.