Wo àwọn àròsọ márùn ún nípa bí o ṣe lè dín ara sísan kù

Oríṣun àwòrán, getty images
Ọpọ eeyan lọkunrin lobinrin lo sanra ju bi wọn ṣe fẹ lọ laye ode oni, ti irufọ awọn eeyan bẹẹ si n wa ọna abayọ bi wọn yoo ṣe din ara sisan naa ku.
Oniruru ọna ni awọn eeyan n gba lanọ ati din ara sisan ku, bi awọn kan ṣe n din ounjẹ alẹ wọn ku lawọn mii kii jẹun lẹyin aago marun un irọlẹ.
Bẹẹ lawọn mii maa n jẹ eso nikan fun ọpọ ọjọ, amọ ti wọn yoo tun sanran pada lẹyin akoko diẹ.
Lọpọ igba ni awọn eeyan n gba oriṣiriṣi ahesọ ọrọ gbọ nipa bi wọn ṣe le din ara sisan ku amọ ti igbesẹ ọrọ ti wọn gbọ kii so eso rere fun.
Wo awọn ahesọ ọrọ ti awọn eeyan n sọ nipa bi o ṣe le din ara sisan ku.
Jije eso ati ẹfọ nikan ṣoṣo

Oríṣun àwòrán, getty images
Awọn kan sọ pe jije eso ati ẹfọ nikan le mu ki eeyan din omi ara ku amọ ṣe lootọi ni?
Ti afojusun rẹ ba jẹ latin din omi ara ku, o ni lati maa woye bi o ṣe n jẹ ohunkohun si, yala ẹfọ ni tabi eso.
Mimu awọn oogun ‘supliments’

Oríṣun àwòrán, getty images
Awọn onimọ ti sọ pe lilo awọn oogun yii nikan ko le din ara sisan ku.
Ṣugbọn o ni lati ṣọra fun awọn ounjẹ aladun bii pizza ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Jijẹ ounjẹ aṣaloore dipo ounjẹ to pọ lapọju

Oríṣun àwòrán, getty images
Lootọ ni ọpọ eeyan gbagbọ pe o san lati jẹ ounjẹ aṣaloore ju ati jẹ ounjẹ to pọju lọna ati din omi ara ku, ootọ ni.
Ṣugbọn ohun to ṣe pataki ni lati din kalori inu ounjẹ ti eeyan n jẹ ku.
Ti o ba n jẹ ounjẹ ti kalori rẹ pọ lapọju, ati din ara sisan ku yoo le diẹ.
Eeeyan yoo nilo owo gọbọi lati jẹ ounjẹ aṣaraloore
Ọpọ eeyan lo lero pe wọn nilo owo gọbọi lati jẹ ounjẹ to n ṣara loore ti ko si ni jẹ ki wọn sanra.
Awọn onimọ ti sọ pe eyii ko ri bẹe rara.
Mimu ọpọlọpọ omi dipo ounjẹ
Ti o ba kọ lati maa jẹun ti o si n mu awọn ohun ẹlẹrindodo dipo rẹ, agọ ara rẹ yoo padanu awọn ohun aṣaloore to nilo.














