Ọkùnrin tó la orí ọmọ ọdún méjì mọ́ ògiri rí ẹ̀wọ̀n gbére he

Zahra Ghulami

Oríṣun àwòrán, KENT POLICE

Ọkunrin kan ti ri ẹwọn gbere he lẹyin to jẹbi iku ọmọ ọdun meji to gba tọ.

Ọmọ ọdun meji naa, Zahra Ghulami, fi ori ṣeṣe nile wọn to wa ni Gravesend lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2020, to si ku lẹyin ọjọ meji.

Iwadii awọn oṣiṣẹ eto ilera lori oloogbe naa fi han pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ṣe ni wọn ju ọmọ naa lu ogiri tabi ki wọn ju u silẹ lai bikita.

Baba oloogbe ọhun, Jan Gholami, to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn jẹbi ẹsun iku ọmọ naa, o tun jẹbi ẹsun wiwu iwa aburu si ọmọde.

Adajọ kan sọ pe o jẹ iwa afurasi lati maa wu iwa ipa si awọn obinrin ninu ẹbi rẹ, o si tọ si lati lọ ṣẹwọn fun ọdun mẹtalelogun o kere tan.

Iyawo Gholami, iyẹn Roqia Ghulami naa yoo tun ṣẹwọn ọdun mẹridinlogun lori ẹsun pe o wu iwa ipa si ẹni ti ọjọ ori rẹ ko tii to ọdun mẹrindinlogun.

Ṣaaju ni obinrin ọhun ti kọkọ jẹbi ẹsun ipaniyan amọ igbimọ adajọ ko fẹnuko lori ijiya rẹ.

Ẹwẹ, tọkọtaya naa sọ niwaju adajọ pe awọn ko jẹbi iku ọmọ ti wọn gba tọ ti wọn fi ẹsun rẹ kan awọn.

Orilẹ-ede Afganistan ni tọkọtaya ọhun ti gba ọmọ naa tọ ki wọn to tẹkọ leti lọ silẹ Gẹẹsi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Adajọ to gbe idajọ naa kalẹ, Justice Wall ni o ṣeeṣe ki Gholami pe ẹrọ ileeṣẹ adoola ẹmi lori nọmba 999 amọ ko ṣe bẹẹ.

Adajọ ni kaka ko gbiyanju lati doola ẹmi ọmọ naa niṣe lo sile itaja igbalode.