Orílẹ̀-èdè Greece fòntẹ̀ lu ìgbéyàwó akọsákọ àti abosábo

Greece

Oríṣun àwòrán, getty images

Orilẹ-ede Greece ti fi ontẹ lu igbeyawo akọsakọ ati abosabo.

Greece ni orilẹ-ede ti awọn Kristẹni ‘Orthodox’pọ si julọ lagbaye, ti yoo kọkọ gbe irufẹ igbesẹ bẹẹ.

Ofin tuntun yii faye gba tọkọkọtaya lati gba ọmọ tọ gẹgẹ bii ti wọn.

Olootu ijọba, Kyriakos Mitsotakis sọ pe ofin to kin igbesẹ naa lẹyin yoo fopin si idẹyẹsi to ti n waye nilẹ naa ṣaaju nipa igbeyawo.

Ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Greece to jẹ ọmọlẹyin Kristi ni ofin naa ko tẹ lọrun, wọn si ti ṣe iwọde tako o niluu Athens.

Pupọ awọn oluwọde naa ni wọn gbe akọle lọwọ wọn, eyii ti wọn fi tako ofin ọhun, ti wọn si n kọ orin inu iwe bi wọn ṣe n ka bibeli niluu Syntagma, to jẹ olu ilu orilẹ-ede naa.

Olori ijọ Orthodox Church nibẹ, Biṣọọbu agba Ieronymos sọ pe igbesẹ ti ijọba gbe naa yoo mu ibajẹ ba ilẹ ọhun.

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn to n ṣatilẹyin fun ibalopọ akọsabo ati akọsakọ ti gboriyin fun igbesẹ naa.

Stella Belia, to jẹ olori ẹgbẹ Rainbow Families sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe inu awọn dun si igbesẹ naa.

Orilẹ-ede marundinlogun ninu orilẹ-ede mẹtadinlọgbọn to jẹ ọmọ ẹgbẹ EU lo ti faye gba igbeyawo akọsakọ ati abosabo.

Nigba ti orilẹ-ede marundinlọgbọn kaakiri agbaye fọwọ si.