Ẹ sì mí gbọ́ ni, kìí ṣe pé mó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó nítorí bí ara mi ṣe n bèèrè fún ìbálòpọ̀- Toyo Baby

Gbajumọ osẹrebinrin, Juliana Olayode, ti ọpọ eeyan mọ si Toyo Baby, ti ṣalaye bi irinajo rẹ sinu ere tiata ṣe bẹrẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC, Arabinrin Olayode sọ pe ẹkọ nipa iṣẹ akọroyin lo wu oun lati ṣe.
Eyi ri bẹẹ nitori pe baba rẹ fẹran lati ma a tẹti si iroyin lori redio ati amohunmaworan.
Olayode sọ pe amọ ala oun ko ṣẹ, nitori pe awọn obi oun ko ri owo san fun ile ẹkọ oun.
“Igba mẹta ni mo ṣe idanwo JAMB, amọ aisi owo jẹ ki n padanu lati fi awọn esi mi wọ fasiti.”
O ni eyi lo mu ki oun bẹrẹ si ni ṣiṣẹ ni ile itaja kan lati tu owo jọ fun ile ẹkọ giga.
Juliana Olayode Toyo Baby di ilumọọka oṣerebinrin nipasẹ ere oniṣe Jenifa’s Diary.
Agba oṣere, Funke Akindele lo ni ere naa.
Toyo Baby sọ pe ipa ti oun ko ninu ere naa lo ṣi ọna fun oun.
Laipẹ yii ni ẹnu kun oṣerebinrin naa nitori ọrọ kan to sọ pe ara oun n wa ibalopọ, ti oun si le ṣe igbeyawo kiakia nitori ki oun le ni ibalopọ.
Ọpọlọpọ eeyan lo bu ẹnu atẹ lu osẹrebinrin naa fun ọrọ to sọ.
Amọ ninu alaye to sọ fun BBC, Olayode sọ pe awada lasan ni oun fi ọrọ naa ṣe, ati pe oun sọ ọ lati le ṣe iwuri fun awọn eeyan bi t’oun, to n pa ara wọn mọ lai fẹ ẹ ni ibalopọ ṣaaju igbeyawo.
“Mo fẹ ki awọn eeyan naa mọ pe kii sẹ awọn nikan ni ara wọn ma n fẹ ẹ ni ibalopọ, amọ o jẹ iyalẹnu pe awọn eeyan kan ṣi ọrọ mi tumọ.
"Eyi ri bẹẹ nitori pe bi eeyan ba ṣe n dagba si i, ni ara rẹ yoo ma a wa ibalopọ botilẹ jẹ pe o ti pinnu lati mu ara duro titi di inu igbeyawo."
Ṣaaju asiko naa ni Arabinrin Olayode ti ma n gba awọn eniyan ni imọran lori ayelujara, lati pa ara wọn mọ.





