'Mo di olùkọ́ èdè Yorùbá nítorí mi ò fẹ́ kó parun, dípò iṣẹ́ amòfin tó wù mí'

Àkọlé fídíò,
'Mo di olùkọ́ èdè Yorùbá nítorí mi ò fẹ́ kó parun, dípò iṣẹ́ amòfin tó wù mí'
Damilare Olabisi

Ẹkọ nipa iṣẹ amofin lo wu Arabinrin Damilare Olabisi Igbayiloye , lati kọ ni fasiti, ṣugbọn ko bọ si i, lo ba pinnu lati ṣe nnkan miran.

Dipo ko yan iṣẹ akọwe mii lati kọ, ẹkọ nipa ede Yoruba lo gba lati ṣe.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Arabinrin Olabisi sọ pe oun gbe igbesẹ naa lẹyin ti oun gbọ ti ajọ UNESCO kede pe, ede Yoruba le parun to ba ya.

Lẹyin eto ẹkọ Damilare, lo da ile ẹkọ Akonilede Yoruba silẹ, nibi to ti n kọ awọn ọmọde ati agbalagba ni Naijiria, ati ilẹ okeere, l’ede Yoruba.

Ori ayelujara ni ile ẹkọ rẹ ti n kọ awọn akẹkọọ wọn ni kika, kikọ ati mimọ ede naa.

O ni awọn to wa ni oke okun ni anfaani naa wa fun ju, nitori pe wọn ko ni anfaani si ede Yoruba ni orilẹede ti wọn wa.

O ni lara awọn ipenija ti ede Yoruba n koju ni bi awọn obi kan ṣe gbagbọ pe ko si oore ti sisọ tabi gbigbọ ede naa le ṣe fun wọn.

O ni awọn anfaani to wa ninu kikọ ede Yoruba pọ ju nnkan to ṣe e fi ẹnu sọ.

Ko ṣa i gba awọn obi ni imọran lati gbaruku ti idagbasoke ede Yoruba nipa lilo agbara imọ ẹrọ igbalode.

Bakan naa lo sọ pe ko ti i pẹ ju fun awọn obi lati bẹrẹ si ni sọ ede abinibi wọn si awọn ọmọ wọn.