Kí ló n fa ikú àìtọ́jọ́ láàrin àwọn ọ̀dọ́ tó n jápa láti Naijiria ní UK?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹnu bi oṣu mẹfa si asiko yii, ko din ni ọmọ Naijiria marun-un, ti iroyin sọ pe o ku ni orilẹ-ede United Kingdom.
Awọn eeyan naa ni iroyin sọ pe ko pẹ pupọ ti wọn de si orilẹ-ede naa lati ma a gbe tabi kawe.
Igbagbọ ọpọ eeyan si ni pe o ṣeeṣe ko jẹ bi oju ọjọ ṣe ri ni orilẹ-ede naa, eyi to yatọ pupọ si ti Naijiria, lo n fa eyi.
Amọ ẹnikan ti oun naa jẹ ọmọ Naijiria, to si ti lo bi ogun ọdun ni UK, Arabinrin Ibironke Adewoye, ṣe atupalẹ awọn nnkan to ni o n fa iru nnkan bẹẹ ati ọna abayọ.
Iru awọn iṣẹlẹ naa lo ni lati bi ọdun 2021 ti ijọba orilẹ-ede UK ṣi anfaani silẹ fun ọpọ eeyan lati wa, ti bẹrẹ.
“Ibanujẹ to wa ninu iku awọn eeyan yii ni pe ọjọ ori wọn kere gan-an, to si jẹ pe awọn ti ko tii ju bi ọdun meji ni orilẹ-ede naa ni.”
“Awọn mẹta lo ku ninu oṣu Kinni nikan.”
O ni lootọ ni ko si aridaju awọn nnkan to n pa wọn, amọ diẹ ti oun le tọka si ni:
Ninu ọrọ to sọ fun BBC, Arabinrin Adewoye sọ pe pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria, to ṣẹṣẹ japa lọ si United Kingdom, lo jẹ obitibiti gbese owo ti wọn fi gbọ bukaata irinajo wọn.
Yatọ si eyi, o ni orilẹ-ede UK ko dabi i ti tẹlẹ mọ, paapaa nipa ti ipese iṣẹ.
Arabinrin tun sọ pe iṣẹ aṣeju, ati bi awọn eeyan kan kii ṣe sinmi daadaa, tun le fa a . to jẹ oṣiṣẹ ilera sọ pe iru awọn nnkan bẹẹ n fa oriṣiriṣi aisan si agọ ara, to si le fa ẹmi kukuru.
Bakan naa lo sọ pe awọn eeyan kan ti ni aisan lara tẹlẹ ki wọn o to o japa, amọ ti wọn ko mojuto daadaa.
“Aisi anfaani lati tete ri dokita naa tun wa lara nnkan to n fa a .”
Arabinrin Adewoye tun fi ẹsun kan awọn mọlẹbi awọn eeyan naa to wa ni Naijiria, pe wọn n di bukaata to pọ ju le awọn ọmọ wọn to wa ni UK lori.
O ni kii ṣe pe wiwa si ilu oyinbo jẹ nnkan to buru, o ni ṣugbọn o gba ọgbọn.
Imọran to gba awọn eeyan ni pe ki ọkọ tabi iyawo kọkọ wa, ko to o di pe ẹbi rẹ darapọ mọ.
Ẹwẹ, o ni o ṣe koko ki awọn eeyan mọ pe iṣẹ idọti lo ṣeeṣe ki wọn o kọkọ ṣe, ki wọn si pese ọkan wọn silẹ.





