Ẹ kọ̀wé fipò sílẹ̀ tí ìṣòro Nàìjíríà bá ga jù yín lọ - Àwọn Gómìnà PDP sì Tinubu, APC

Oríṣun àwòrán, others
Awọn Gomina labẹ orule ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti kesi ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ati Aarẹ Bola Tinubu lati kọwe fipo silẹ ti wọn ko ba le wa ojutu si bi nnkan se le koko lorilẹede Naijiria lasiko yii.
Lara awọn iṣoro ti orilẹede Naijiria n koju ni ọwọngogo ounjẹ ati ọrọ aje to mẹyẹ eyi to jẹ inira fun awọn ọmọ Naijiria lati ra ounjẹ.
Alaga awọn gomina naa to tun jẹ gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed salaye pe Orilẹede Naijiria labẹ Aarẹ Bola Tinubu ti n tọpasẹ lati da bi orilẹede Venzuela.
Ninu ọrọ rẹ, eyi ti agbẹnusọ, Cyril Maduabum fi lede fun awọn akọroyin gba ijọba apapọ ni amọran lori igbesẹ ti ijọba apapọ ati ipinlẹ le gbe lati wa ojutu si isọro ọwọngogo yii.
Maduabum ni amọran ati iba ti awọn fun ijọba lo wa lati ọdọ awọn ẹgbẹ gomina ti inu wọn ko dun si bi nnkan se wa lorilẹede Naijiria.
“Iya ti awọn Naijiria n jẹ lọwọ bayii ni ko mọ ẹya, ẹṣin tabi ẹgbẹ oṣelu.
“Gbogbo ẹka ijọba pata lo ni isẹ lati ṣe , ẹgbẹ oṣelu APC ni lati ko gbogbo wa pọ ati awọn ẹka ijọba lati wa ojutu si iṣoro yii.
“Ti wọn ba kuna lati se eyii tabi wọn ko ni agbara lati se, wọn le kọwe fipo silẹ."
Saaju mi Minisita fun eto iroyin, Mohammed Idris bu ẹnu atẹlu bi ẹgbẹ Gomina labẹ asia PDP se fi orilẹede Naijiria we orilẹede Venezuela, to si naaka si awọn Gomina PDP pe pupọ wọn lo kuna lati se ojuse wọn nipa sisan owo oṣu awọn osisẹ , owo ifẹyinti ati awọn owo mii.
Nigba ti wọn si ọrọ naa, ẹgbẹ awọn Gomina ni awọn minisita kan se bu ẹnu atẹlu ẹgbẹ oṣelu PDP fun bi wọn se n gbero to da fun Naijiria ni ko by jumu rara nitori pe ẹgbẹ oṣelu APC se ilera lati yanju gbogbo iṣoro Naijiria ki i se lati da awọn kan lẹbi.
“Ti a ba n sọrọ nipa awọn ipinlẹ to eto iṣejọba dara ju, ẹgbẹ oṣelu ti PDP ti jẹ Gomina, ti wọn si n san owo oṣu awọn osisẹ deede.”















