Wo ọ̀nà tí ìjọba fẹ́ gbà láti gbọn ìṣẹ́ dànù lára ọmọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/X
Minisita fọrọ eto iṣuna lorileede Naijiria, Wale Ẹdun ti sọ pe ijọba ti n gbe awọn igbesẹ lati yanju awọn iṣoro ati ipenija eto ọrọ aje ti araalu n koju lasiko yii.
Ọgbẹni Ẹdun mẹnu ba oriṣiriṣi ọna ti iṣoro gba wọ Naijiria, eyi to mu ki igbe aye le koko fun araalu nipa ounjẹ jijẹ, ọwọngogo, aisi eto aabo, aisi owo ati awọn miran.
Ọjọ Ẹti to kọja ni minisita feto iṣuna, ẹni to tun jẹ minisita alabojuto fun eto ọrọ aje Naijiria sọrọ naa nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Channels.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọwọngogo to n ṣẹlẹ kaakiri orileede Naijiria lati igba ti Aarẹ Bọla Tinubu ti yọ owo iranwọ ori epo ti mu ki ọpọ araalu bẹrẹ ifẹhonuhan kaakiri, lati kepe ijọba fun ọna abayọ.
Ẹdun sọ pe awọn ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu banki agba ilẹ Naijiria fun ọna abayọ ti yoo din ọwọngogo ku, ti eto aabo yoo si wa fun ounjẹ ti araalu n jẹ.
O sọ ninu ọrọ rẹ pe “ohun ti mo ro pe o ṣe pataki lati sọ lasiko yii ni pe owo ounjẹ ti lọ soke gidi, ti gbogbo wa si mọ ohun fa a.
O jẹ fun ti a gbọdọ reti nipa bi owo nnkan ṣe lọ soke gẹgẹ bi ohun ti yoo jẹyọ, ṣugbọn ti igbesẹ ọna abayọ lati ṣatunṣe nipa fifi eto ọrọ aje soju ọna to yẹ ko wa.”
Ẹdun tẹsiwaju pe ọna ti ijọba n gba ni lati mu adinku ba iṣoro wọnyi, paapaa fun awọn alaini ati awọn to ku diẹ kaato fun kaakiri Naijiria.
“Mo ro pe o ṣe pataki lati sọrọ jade lasiko yii, nitori pe afojusun Aarẹ ni lati mu awọn ileri rẹ ṣẹ, paapaa fun awọn alaini ati awọn to ku diẹ kaato fun.
“Owo ounjẹ ti lọ soke, ina mọnamọna si ree, ko to, idi si ree ti Aarẹ fi n sọrọ nipase eto iranwọ kan ti wọn ti fẹ maa fun awọn eeyan ẹgbẹrun marundinlọgọrin (N75,000) naira fun oṣu mẹta.
“Iyẹn ni pe ile kọọkan ti ko din ni miliọnu mẹẹdogun yoo gba ẹgbẹrun marundinlọgbọn (N25,000) naira. Awọn eeyan inu ile kọkọkan ko si gbọdọ din ni marun-un.
“Eleyi lo tunmọ si pe eeyan miliọnu marundinlọgọrin ni yii jẹ anfaani eto iranwọ yii.”
Bakan naa lo tun sọ pe ijọba apapọ tun gbero lati pin awọn ire oko, ti yoo mu irọrun ba araalu, ti ebi yoo si di ohun igbagbe.
“Laipẹ yii ni ijọba apapọ pin ẹgbẹrun mejilelogoji tirela ounjẹ kaakiri, ti ọgọta miran si tun n bọ laipẹ. Eyi ni lati jẹ ki ounjẹ pọ yanturu laarin ọja.















