Irọ́ ni pé a kọlu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ KWASU l'Ọjọ́bọ, bí ọ̀rọ̀ ṣe rí rèé...

Ajọ to n gbogun iwa jibiti ati ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, sọ pe awọn oṣiṣẹ rẹ ko yìnbọn mọ akekọọ kankan ni fasiti ipinlẹ Kwara.
Alẹ Ọjọbọ ni iroyin gba ori ayelujara pe, wahala ṣẹlẹ nile-ẹkọ giga fasiti ijọba ipinlẹ Kwara, iyẹn KWASU to wa niluu Malete, ijọba ibilẹ Moro, ipinlẹ Kwara.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn akekọọ KWASU lo tu jade lati fi ẹhonu wọn han lori bi ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, EFCC ṣe ya wọ ibugbe awọn akẹkọọ naa.
Nigba ti wọn yoo fi kuro nile ẹkọ naa, akekọọ KWASU ti ko din ni aadọta ni wọn ko lọ.
Koda, iroyin naa sọ pe wọn yinbọn mọ awọn akekọọ kan.
Ṣugbọn ninu atẹjade kan to fi si ori ayelujara Twitter rẹ ni ọjọ Ẹti, EFCC sọ pe agbelẹro ni iroyin naa ti awọn ileeṣẹ iroyin kan gbe jade.
O ni ko si nkan to jọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa ni ẹkun Ilorin, lọ si fasiti ipinlẹ Kwara, tabi ṣe ajọṣepọ iṣẹ pẹlu àjọ to n gbogun ti oogun oloro, NDLEA, ni Ọjọbọ, ọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun 2024.
"Akanṣe iṣẹ kan ṣoṣo ti ajọ yii ṣe, waye ni Ọjọ́rú, nibi ti a ti mu akẹkọọ mejidinlaadọta lati Fasiti ipinlẹ Kwara."
EFCC sọ pe ilana to bojumu ni oun fi ṣiṣẹ. Bákan naa lo ni iṣẹ adaṣe ni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
EFCC àti NDLEA kó akẹ́kọ̀ọ́ 50, ọkọ̀ mẹ́sàn-án ní fásitì KWASU, wàhálà bẹ̀rẹ̀

Nnkan ko fara rọ l’Ọjọbọ nile-ẹkọ giga fasiti ijọba ipinlẹ Kwara, iyẹn KWASU to wa niluu Malete, ijọba ibilẹ Moro, ipinlẹ Kwara.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn akekọọ KWASU lo tu jade lati fi ẹhonu wọn han lori bi ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, EFCC ṣe ya wọ ibugbe awọn akẹkọọ naa.
Nigba ti wọn yoo fi kuro nile ẹkọ naa, akekọọ KWASU ti ko din ni aadọta ni wọn ko lọ.
Ẹsun to nii ṣe pẹlu lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara ni wọn sọ pe ajọ EFCC fi kan awọn akẹkọọ tọwọ tẹ naa.
Yatọ si pe wọn ko awọn akẹkọọ wọnyii, ajọ EFFC tun gba ọkọ bọginni ti ko din ni mẹsan lọwọ gbogbo wọn.

"Ajọ to n gbogun ti lilo egbogi oloro (NDLEA) naa tun ya wọ ilegbe awọn akekọọ"
Lasiko ti asoju akọroyin ile isẹ wa (BBC) Yoruba kan si ọgba ile ẹkọ naa, ṣe ni awọn akekọọ n fi ibẹru bojo han lori iṣẹlẹ naa.
Ọkan lara awọn akekọọ ile-ẹkọ naa to ba BBC Yoruba sọrọ, omidan Prosper Ọdẹyẹmi ṣalaye pe iṣẹlẹ naa da ibẹru sọkan awọn.
Akẹkọọ mii to tun sọrọ, omidan Mercy Inawọle ati Garuba Mohammed ni, ṣe làwọn akekọọ n sa asala fẹmi ara wọn lasiko isẹlẹ naa.
O fi kun ọrọ rẹ pe, yatọ si ti ajọ EFCC to n mu awọn akekọọ ti wọn lo n se Yahoo, ṣe ni awọn ajọ to n gbogun ti gbigbe egbogi oloro NDLEA) naa tun ya wọ ilegbe awọn akekọọ.
"Ko si akekọọ kankan ti wọn yinbọn mọ tabi farapa"
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, alukoro fun ileesẹ Ọlọpa ipinlẹ Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Toun ṣalaye pe, awọn Ọlọpa kan to wa si Malete lati ilu Ila Orangun ni ipinlẹ Osun, ni awọn akekọọ naa ri, ti wọn ro pe awọn (NDLEA) ni.
O ni se ni wọn bẹrẹ si ni pariwo le wọn lori, bẹẹ ni wọn ju okuta lu ọkọ awọn ọlọpa naa.
Ninu ọrọ tiẹ, akọwe agba ile ẹkọ giga fasiti ijọba ipinlẹ Kwara, Ọmọwe Kikẹlọmọ Salle sọ pe alafia ti pada bọ sinu ọgba ile ẹkọ naa.
Bakan naa lo sọ pe ko si akekọọ kankan ti wọn yinbọn mọ, akekọọ kankan ko si farapa.
O fikun pe igbimọ Alasẹ ile ẹkọ naa ti kan si ajọ (EFCC) ati (NDLEA) lati jọ sisẹ pọ lọna ti ohun gbogbo yio fi lọ lalafia.
















