EFCC yawọ Sabo n‘Ibadan, tí wọ́n ti n ṣẹ Dollar, ọwọ́ tẹ oníṣòwò mọ́kànlá

Aworan ibi isele naa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbesẹ ti ijọba apapọ orilẹede Naijiria n gbe lati wa ojutu si aisan to n ṣe Naira owo ilẹ wa, o kere tan, awọn oniṣowo mejila ọtọọtọ to n ṣe karakata Dollar owo ilẹ okere ni ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lẹka eto iṣuna, EFCC ti nawọ gan ni agbegbe Sabo niluu Ibadan.

Ninu iwọde ti ajọ naa ṣe pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn agbofinro mii l'Ọjọru ni nnkan bii aago mẹwaa si mọkanla owurọ, bii mejila lara awọn to n ṣe karakata owo Dollar ni ajọ EFCC ko lọ.

BBC Yoruba kan si ẹgbẹ awọn oniṣowo to n parọ owo ilẹ okere ti ọpọ eeyan mọ si 'Bureau De Change’ ni agbegbe Sabo niluu Ibadan lẹyin iṣẹlẹ naa.

Ọpọ lara awọn to n ṣẹ Dollar si Naira ni ko ri owo ṣẹ mọ

Bo tilẹ jẹ wi pupọ awọn ti ori ko yọ lara awọn oniṣowo naa ti sa kuro ni agbegbe Sabo lati igba ti ajọ EFCC ti ko awọn akẹgbẹ wọn lọ, a ri alaga ẹgbẹ awọn to n ta Dollar naa, Alhaji Aminu Ibrahim Babankande ba sọrọ.

Babankande ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe ibi ti ijọba Naijiria fi oju si, ọna ko gba ibẹ nitori pe pupọ lara awọn to n parọ owo Dollar si Naira gan an ni ko ri Dollar gba mọ lẹnu ọjọ mẹta yii.

O ni awọn ọwọngogo Dollar de ọdọ awọn naa, ti o tumọ si wi pe ọdọ awọn kọ ni idamu to ba owo Naira ti bẹrẹ.

O ni, "Wọn ko awọn ọmọ ẹgbẹ wa kan lati ana, a si ti n gbiyanju lati gba wọn pada ṣugbọn ajọ EFCC ko tii fi wọn silẹ, a ko si mọ iredi naa.

Awa kọ ni a ni ki Dollar wọn, awa gan ko ri Dollar si oju o si n pa okoowo ti wa naa lara. Titi di aarọ oni, a ṣi n wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ wa kan ti a ko mọ boya akata EFCC ni wọn ṣi wa tabi wọn ti pada sile wọn."

O fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn ṣetan lati fi ọwọ sowọpọ pẹlu ijọba lori gbogbo iwadii ti wọn ba fẹ ṣe.

A gbe alaye sita lori idi ta fi lọ sọja Sabo ni Ibadan - EFCC

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ agba ninu ajọ EFCC fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ pẹlu alaye wi pe ajọ naa yoo ṣe atejade pẹlu alaye kikun fun awọn oniroyin laipẹ.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni owo Naira bẹrẹ sini gbokiti ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu owo Dollar ilẹ okere. Naira ja walẹ de ibi to ti n ṣunmọ ẹgbẹrun meji si Dollar kan.

Eyii lo mu ki ijọba apapọ orilẹede Naijiria bẹrẹ sini gbe awọn igbesẹ to le mu ojutu wa si iṣoro to n koju owo ilẹ wa.

Ilu Ibadan nikan kọ si ni ajọ EFCC ti ṣoro bi agbọn fun awọn to n ta Dollar. Ajọ naa ti ko awọn to n ta Dollar niluu Abuja, Kano, Port Harcout, ati Enugu.