Ìṣòro tó ń kojú aráàlú pọ̀jù, ẹ má yọwó ìrànwọ́ tàbí gbé èlé gorí owó iná ọba – Ilé aṣòfin àpapọ̀

Osisẹ ina ọba gun ori opo

Ile igbimọ aṣofin agba Naijiria ti sọ pe awọn ko nii gba ẹkunwo lori owo ina mọnamọna ti ileeṣẹ to n mojuto ọrọ agbara ina lorileede yii gbe wa siwaju wọn.

Awọn to ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna kaakiri Naijiria la gbọ pe wọn gbe aba lati fi owo kun owo ina mọnamọna ti awọn araalu n lo naa lọ siwaju ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri sọrọ agbara ina lati buwọ lu.

Bakan naa ni ile igbimọ aṣofin agba tun sọ pe ko si ohun to jọ ọ lati yọ owo iranwọ ori ina mọnamọna, lati le fi owo kun un, ko le lọ soke ju ti tẹlẹ lọ.

Ile igbimọ aṣofin agba ti wa pe ijọba apapọ lati gbagbe nipa erongba lati fi owo kun owo ina mọnamọna lasiko yii, pẹlu bi awọn araalu ṣe n koju iṣoro igbe aye to rọrun.

Siwaju sii ni ile igbimọ ọhun tun paṣẹ pe ki igbimọ to n ri sọrọ ina mọnamọna bẹrẹ iṣẹ iwadii lori tiriliọnu meji naira to jẹ owo iranwọ ori owo ina mọnamọna, awọn gbese miran ati ipo ti pinpin awọn mita (metre) f’awọn araalu de duro.

"ijọba Naijiria ni oun ko le tẹsiwaju mọ lati maa san owo iranwọ ori ina mọnamọna"

Eyi lo waye lẹyin aba ti Sẹnetọ Aminu Abbas to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun Adamawa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP da wi pe ki wọn ma ṣe yọ owo iranwọ ori ina mọnamọna lati le jẹ ki awọn araalu tẹsiwaju lati maa jẹ mudunmudun eto iṣejọba awarawa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọsẹ to kọja ni minisita fọrọ ohun amusagbara, Adebayọ Adelabu sọ nibi ipade ipade oniroyin to pe, to si jẹ ko di mimọ pe ijọba Naijiria ko le tẹsiwaju mọ lati maa san owo iranwọ ori ina mọnamọna.

Nibẹ lo ti ṣalaye pe gbese ti ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna, iyẹn electricity-generating companies (GenCos) ati ileeṣẹ to n pese afẹfẹ gaasi, gas companies (GasCos) ti jẹ ti le ni tiriliọnu mẹta naira.

O ni tiriliọnu kan le ni ọọdunrun (N1.3tn) ni ijọba jẹ ileeṣẹ GenCos, nigba ti ida ọgọta jẹ eyi ti wọn jẹ ileeṣẹ to n pese afẹfẹ gaasi, GasCos.

Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin naa, Yẹmi Adaramodu nigba to n sọrọ, sọ pe awọn ko nii jẹ ki iṣoro to n koju ọmọ Naijiria tun le sii, bi ko ṣe pe ki wọn wa ọna abayọ.

Adaramodu sọ pe owo to le ni tiriliọnu meji naira lawọn nilo lati fi san owo iranwọ, ṣugbọn to ni biliọnu lọna aaadọtalenirinwo (N450bn) lawọn ṣe akọsilẹ rẹ lati na lọdun yii.

Bakan naa lo ni awọn ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna yii kan n gba owo lọwọ awọn onibara wọn lasan ni lori ina ti wọn ko lo, pẹlu bi wọn ko tun ṣe fi kun iṣẹ ti wọn n ṣe to.