Ẹkún, ìbànújẹ́ àti ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe sin Akeredolu l’Ondo

Oríṣun àwòrán, Olawale Abolade
Gomina ana nipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimim Akeredolu ti bẹrẹ irin ajo tuntun lọ sinu aye miran.
Ara, ọrẹ, ojulumọ ati awọn alabaṣepọ lo korajọ lati ṣẹyẹ ikẹyin fun un loni, ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun 2024.
Ile ijọsin St. Andrew Cathedral to wa nilu Ọwọ to jẹ ilu abinibi Akeredolu ni eto isinku naa ti waye.
Ọpọ awọn eeyan to wa nibẹ ni wọn kọminu, ti wọn banujẹ lori ipapoda Gomina Akeredolu, ẹni ti wọn lo ṣiṣẹ takuntakun ninu idagbasoke ipinlẹ naa, paapaa lẹka eto aabo.


Oríṣun àwòrán, Awon to banuje/BBC
Igbakeji aarẹ Naijiria, Kashim Shettima, ati ọpọ awọn gomina lo wa nibẹ lati wo bi akẹgbẹ wọn tẹlẹ ṣe fẹẹ wọ ka-ilẹ sun.
Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa lo lewaju gbogbo awọn gomina patapata.
Lara awọn gomina naa ni Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ; Godwin Obaseki ti ipinlẹ Ẹdo; Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko.
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni Naijiria, Abdullahi Ganduje; Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima; Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Ogun ati Ondo, Kayọde Fayẹmi; Sẹnetọ Gbenga Daniel ati Olusegun Mimiko ko gbẹyin nibẹ.
Bakan naa ni Gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetola ati awọn miran naa wa nibẹ pẹlu.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Akeredolu ni alaga ana fun ẹgbẹ awọn gomina ẹkun Iwọ-Oorun Naijiria nigba to wa laye.
Oun naa si ni igi lẹyin ọgba fun idasilẹ ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun lati gbogun ti awọn agbebọn ati ajinigbe.
Aṣọ Amọtẹkun naa ni wọn tun gbe sori poosi rẹ, lati fi yẹ ẹ si.

Bí àìsùn onígbàgbọ́ fún Akeredolu ṣe lọ rèé bó se ń wọ káà ilẹ̀ sùn lónìí

Oríṣun àwòrán, BBC/ROTIMIAKEREDOLU
Nigba ti wọn gbe oku Gomina ana nipinlẹ Ondo to ti di oloogbe, Rotimi Akeredolu SAN, CON de si ilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo, lọjọru, ọjọ kọkandinlogun oṣu keji ọdun 2024, ọpọ eeyan lo pejọ ti wọn si n tomije loju.
Wọn gbe oku naa wọle pẹlu tọwọtọwọ bi ti ọga ologun gẹgẹ bi o ṣe jẹ pe o di ipo nla mu nipinlẹ Ondo ti awọn araalu si n bu ọla ikẹyin fun gomina tẹlẹ naa.
Lọjọru ọsẹ yii, wọn bẹrẹ pẹlu isin idagbere ni ileẹjọ gẹgẹ gẹgẹ bii amofin ti gomina tẹlẹ naa jẹ, ki wọn to gbe oku naa lọ si paapa iṣere ti ilu Akure.
Gẹgẹ bii ọpọ araalu ṣe sọ, ẹlẹyinju aanu ni Arakunrin Rotimi Akeredolu nigba aye rẹ.
Lasiko isin idagbere, ọpọ awọn ilumọka lo wa ni ikalẹ, ti ọpọ araalu naa si wa lati wa wo gomina tẹlẹ naa ko to wọ kalẹ.

Oríṣun àwòrán, RICHARD OLABODE
Awọn araalu ni pẹlu bi o ṣe jẹ pe Akeredolu ti jade laye, yoo si wa ninu akọlẹ pe o jẹ olori to ni afojusun rere fun ilu.
Nigba to n sọrọ, Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa ni ọga ohun jẹ olori to ni iwa rere, to si nifẹ ilu rẹ pupọ.
Aiyedatiwa ni oloogbe ti lọ sun, ti ko dẹ ni pada wa mọ, fun idi eyi awọn lati bu ikẹyin to lamilaka fun un.
“Itan igbesi aye Akeredolu sọ nipa irubọ ati ọkan akin to se ati awọn ipa rere silẹ to fi lelẹ.
“Mo ranti gbogbo nnkan ti ọkunrin nla to wa nilẹ yii gbe ṣe fun wa lasiko ti ijinigbe ati ikọlu awọn darandaran wọpọ lorilẹede wa,”
Oku Akeredolu de si ilu Owo.

Oríṣun àwòrán, RICHARD OLABODE
Tilu tifọn, omije ati ariwo ẹkun ni awọn araalu fi pade oku Gomina ana Rotimi Akeredolu niluu Owo.
Wọn bẹrẹ pẹlu etutu Ajabue, ti ọpọ agbegeb to wa ni ilu Owo lo wa ni titi pa nitori ọpọ eeyan fẹ oku naa bi wọn se gbede.
Agbegebe Emure niluu Owo kun fun ero bi ilu ṣe tẹwọgba oku Akeredolu pẹlu iyi ati ọwọ.
Orin Aketi ni ọpọ awọn araalu mu bọ ẹnu.
Ọkọ to gbe oku naa kiri kaakiri ilu, ti awọn akẹkọọ si n juwọ odigba si ọkọ naa.

Oríṣun àwòrán, RICHARD OLABODE
Oni ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ni Akeredolu yoo wọ kalẹ

Oríṣun àwòrán, RICHARD OLABODE
O jade laye niluu Germany, ti wọn si gbe oku pada si orilẹede Naijiria ni ọjọ karun un oṣu kini ọdun 2024.
Awọn eeyan to wa ni bi isin idagbere naa Iyawo oloogbe Betty Anyanwu Akeredolu, Adajọ Bolaji Olajuwon, Oluwarotimi Odunayo Akeredolu Jnr, Babajide Akeredolu, Lady Ifeoma Atuegwu, Dr Teniola Akeredolu-Micheals ati Pastor Kola Akeredolu.
Awọn yooku ni Igbakeji Gomina, Olayide Adelami, Gomina ana nipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi, igbakeji gomina télẹri nipinlẹ Osun, Iyiola Omisore, abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo, Olamide Oladiji, alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ondo, Ade Adetimilẹyin ati awọn eekan mii.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Akeredolu to d'oloogbe
Akeredolu jade laye lẹyin aarẹ to ti ba finra fun igba diẹ.
Ohun ni Gomina ipinlẹ iwọ oorun Naijiria keji ti yoo ku lori oye.
Ninu itan oloṣelu Naijiria awọn eeyan ko ni gbagbe Rotimi Akeredolu to jẹ akọṣẹmọṣẹ agbẹjọro agba to si tun jẹ gbajugbaja oloṣelu ni Naijiria.
O fi iyawo ati awọn ọmọ silẹ lọ.
Ọdun 1956 ni wọn bi Oluwarotimi Odunayo Akeredolu to si jẹ ọmọ ilu Owo ni ipinlẹ Ondo.
Arakunrin ni inagijẹ rẹ ti ọpọ a maa fi pe paapa lagbo oṣelu ipinlẹ Ondo nibi to ti jẹ Gomina fun saa ẹmeeji ọtọọtọ.
Ile ẹkọ ibẹrẹ Government School lo ti bẹrẹ ẹkọ rẹ to si tẹsiwaju lati ibẹ lọ si St Aquinas College, Loyola College ni Ibadan ati Comprehensive High School Aiyetoro nibi to ti gba sabuke ile ẹkọ girama.
FasitiObafemi Awolowo ni Ile Ife lo ti kẹkọ nipa imọ ofin to sipari ẹkọ rẹ lọdun 1977.
Ọdun 1978 ni wọn pe si ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorileede Naijiria.















