Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi máa ń tijú láti wọ aṣọ ilé ẹ̀kọ́ wọn ló jẹ́ kí n máa wọ̀ ọ́ - Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́

Àkọlé fídíò, ''Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi máa ń tijú láti wọ aṣọ ilé ẹ̀kọ́ wọn ló jẹ́ kí n máa wọ̀ ọ́''
Aworan ọgagba ile ẹkọ ati akẹkọọ

Yoruba bọ wọn lẹnu iṣẹ ẹni ni aa ti mọ ẹni lọlẹ, eyi lo difa fun ọgbagba ilẹ ẹkọ girama C$S to wa ni Sabo Oke niluu Ilorin, Arabinrin Ogunbiyi Christiana Oluwayemisi ti o wọ aṣọ ile ẹkọ bi awọn akẹkọọ rẹ.

Ọgagba ile ẹkọ naa ṣalaye fun BBC wi pe ''pupọ ninu awọn akẹkọọ mi ni oju n ti lati maa wọ aṣọ ile iwe wọn.

Idi niyii ti emi gan an fun ra mi fi bẹrẹ sii wọ aṣọ naa ki wọn le maa wọ ọ daadaa.

Ko si ohun ti o fi n ṣe eeyan, koda wiwọ aṣọ ile ẹkọ maa n fun eeyan ni iyi si ni.''

Ọgagba ile ẹkọ C&S ni ''Eto ẹkọ asiko yii ti yatọ si ti ijọun.

Ni ti ijọun, ti awọn akẹkọọ ba ri olukọ lasan, ipaya wa fun wọn.

Kii ṣe ẹru wi pe o fẹ pa wọn jẹ o, ṣugbọn ẹru bi igba ti a le pee ni ibọwọ fun ni.

Wọn o ni le kọja niwaju olukọ nibi ti o ba duro si, ṣugbọn nisinyii, awọn akẹkọọ maa duro ti olukọ ni.

Ko si ẹru mọ, wọn o ka olukọ si, ki a wa tiẹ wa sọ olukọ agba.

Bi o tiẹ mu ẹgba dani gan an. Ko dẹru bawọn, eyi ti ko si tọ ti ko si yẹ ki a lo nitori wọn ki i ṣe ẹranko.

Oge aṣeju, a n sọ fun wọn, paapaa awọn obinrin.

Ko tii to asiko, ẹ mu suuru, nigba ti asiko ba de, ẹ o kọja lori afara si apa keji.''

Amọ, Arabinrin Ogunbiyi sọ pe pupọ ninu akẹkọọ ti n rii pe otitọ wa ninu ohun ti awọn olukọ n sọ fun wọn.

Ọgagba ile ẹkọ naa ṣalaye pe ọjọ ti inu oun dun julọ lọjọ ti oun ba ọmọ ti oun ti kọ nile ẹkọ ri pade to ti di dokita oniṣegun oyinbo.