Ìyàwó mi Ropo ni wọ́n lò láti mú mi ní Benin Republic - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho
Gbajugbaja ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ti ṣalaye nipa bi ọwọ awọn agbofinro ṣe tẹ ẹ ni orile-ede Benin Republic.
Nibi ayẹyẹ isinku iya rẹ, to waye n'ilu Igboho nipinlẹ Oyo, l'Ọjọ́bọ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ni Igboho ti tu kẹ̀kẹ́ ọrọ silẹ.
Ninu alaye rẹ lo ti sọ pe,iyawo oun keji, Arabinrin Ropo Adeyemo, ni awọn ọlọpaa orile-ede naa lo lati mu oun.
Ki lo gbe Sunday Igboho kuro ni Naijiria?
Oru mọjumọ ọjọ kini, oṣu keje, ọdun 2021 ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS lorileede Naijiria lọ kọlu ile Sunday Igboho, nibi ti wọn ti pa awọn meji, ti wọn si ko awọn mẹtala lọ siluu Abuja.
Gboho ile naa ni wọn fi ibọn bajẹ, to fi mọ awọn mọto to wa ninu ile naa, ti ẹjẹ si bo gbogbo ilẹ inu ile si ayika inu ọgba ile Igboho.
DSS ni awọn pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo miran ni wọn jọ ṣiṣẹ papọ lati kọlu Igboho, ṣugbọn to poora mọ wọn lọwọ.
Ẹsun ti DSS fi kan Igboho ni pe o n ko ibọn ati awọn ohun ija oloro pamọ lati da ogun silẹ laarin ilu.
Lara awọn ohun ti wọn ko ni iwe irinna, ibọn, awọn aṣọ oogun loriṣiriṣi, to fi mọ ologbo.
'Iyawo mi ti a jọ n rinrin ajo ni wọn fi mu mi'
Oloye Sunday Igboho ni o wu ki oun ri iya oun ko to ku, sugbọn Ọlọrun lo ni ẹmi.
Igboho sọ pe ki iya oun to ku, o rọ oun lati pada wa sile niwọn igba ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti kuro nipo.
"Iya mi sọ pe orúkọ Tinubu ko nii parun ninu itan Yoruba, to ba fi pa mi."
O salaye pe iya agba naa ṣe ileri lati bẹ Ọlọ́run fun itusilẹ oun, amọ alẹ ọjọ naa gan-an ni iya naa bẹrẹ aisan to pada gba ẹmi rẹ.
"Ọjọ kẹta ti iya mi ku ni mo gba ominira ni Benin Republic.
" Aarẹ wọn ni ki wọn lọ pe mi wa. Nigba ti mo de ibẹ̀, o ni oun ri i ka ninu iwe iroyin pe iya mi ku.
" O ni oun mọ pe nnkan ti oun ṣe dùn mi, amọ mo jẹ ko ye e wi pe, kadara mi ni nnkan to ṣẹlẹ nitori pe kii ṣe awọn lo mu mi fúnra wọn"
Sunday Igboho salaye pe nigba ti wọn da oun duro ni Benin Republic, òun sọ fun iyawo oun ti awọn jọ wa nibẹ pe oun le kuro laarin awọn ọlọpaa, lai si ẹni ti yoo ri oun.
"Emi ati iyawo mi kan la jọ wa níbẹ̀. Bi mo ṣe kuro laarin wọn, wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si iyawo mi lọwọ.
" Mo pe iyawo mi keji lati sọ fun pe wọn ti mu orogun rẹ. Kia lo sọ fun mi pe ki n pada sibẹ lati lọ gba a silẹ.
O ni Iyawo oun sọ pe ki oun lọ fa ara oun kalẹ, nitori pe oun nikan l'oun n ṣe Yoruba Nation.
" Mo pe awọn baba mi, wọn ni mi o gbọdọ pada. Bẹẹ naa ni iyawo mi n pariwo mọ mi lori foonu pe mi o gbọdọ fi orogun rẹ silẹ.
Sunday Igboho sọ pe lootọ ni oun pada si ọdọ awọn ọlọpaa, lati fa ara oun kalẹ, sugbọn wọn kọ lati tu iyawo rẹ silẹ.
" Wọn sọ fun mi pe awọn ko ni yọ̀nda rẹ nitori pe oun ni wọn lo lati mu mi."
Igboho sọ pe ṣẹkẹṣẹkẹ meji ni wọn fi de oun lẹsẹkẹsẹ, ti wọn si gbe oun ju sinu ọkọ.
O ni oun pinnu lati pada sile fun isinku iya oun "nitori oun mọ pe ko si ẹni to le pa oun, ayafi ti Ọlọrun ba sọ pe o ya.
'Ẹ jẹ ka fi òpin si bibu awọn ọba wa nitori Yoruba Nation'
Ajijagbara naa sọ pe oun n ṣe jẹ́jẹ́ bayii nitori awọn iyawo ati ọmọ oun.
"Ka ni mo mọ pe ma a ṣe ijọgbọn laye, mi o ba ma ti fẹ iyawo tabi bimọ."
O ni oun bu awọn ọba nigba ti oun bẹrẹ ọrọ yoruba nation. Ó gba awọn ọmọ ẹyin rẹ ati awọn ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation, lati ma sọ ọrọ ibajẹ si awọn ọba ati ijoye.
Bákan naa lo rọ gbogbo ọmọ Yoruba pe, ki wọn ma ṣe fa wahala, dipo bẹẹ ki wọn fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn agba ilu lati sọ ilẹ Yorùba di ominira.
O ni"a le gba ẹtọ wa lai ṣe ijọgbọn tabi da ilu ru.















