Wo iye owó ti iléẹjọ́ gba béèlì gómìnà Kwara àná,Abdulfatah Ahmed lórí ẹ̀sùn màgòmágó

Aworan Abdulfattah Ahmed niwaju ile ẹjọ giga

Oríṣun àwòrán, Radio Kwara

Ile-ẹjọ giga ti ijọba apapọ to kalẹ si ilu Ilọrin, olu-ilu ipinlẹ Kwara ti gba beeli ati oniduro fun gomina ipinlẹ ọhun tẹlẹri, Abdulfatah Ahmed lori ẹsun ṣiṣe owo ilu mọkumọku fi wọn fi kan an.

Ọjọ Ẹti to kọja, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun ti a wa yii ni igbẹjọ ọhun ti waye niwaju onidajọ Evelyn Anyadike.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti, ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) lo fẹsun kan Abdulfatah Ahmed ti ọpọ mọ si Maigida niwaju ile-ẹjọ.

Ẹsun owo ti ko din ni biliọnu mẹwaa Naira ni ajọ EFCC sọ pe Abdulfatah Ahmed ṣe mọkumọku lasiko to wa nipo gẹgẹ bii gomina, iyẹn laarin ọdun 2011 si 2019.

Ahmed ati kọmiṣana feto iṣuna ipinlẹ Kwara lasiko iṣakoso rẹ, Ọgbẹni Ademọla Banu ni ajọ EFCC jọ wọ lọ siwaju ile-ẹjọ lati ṣalaye bi wọn ṣe owo naa.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Ademọla Banu kọ lati yọju si ile-ẹjọ, bẹẹ si ni ko ran agbẹjọro kankan lati wa duro fun un.

Lẹyin gbogbo ọrọ awọn agbẹjọro ijọba ati olujẹjọ, Onidajọ Evelyn Anyadike nigba to n sọrọ gbe ilana mẹjọ gboogi kalẹ fun olujẹjọ naa lati gba ominira.

Onidajọ Anyadike tẹsiwaju pe ki Ahmed san aadọta miliọnu naira lati gba beeli ara r’ẹ pẹlu oniduro meji ọtọọtọ ti wọn ni dukia ori ilẹ layika ile-ẹjọ.

Bakan naa lo fi kun un pe ki Ahmed wa lakata ajọ EFCC titi ti yoo fi ri gbogbo awọn ilana yii.

Siwaju sii ni Anyadike paṣẹ pe ki Abdulfatah Ahmed yọnda iwe irina rẹ ati awọn ilana iyoku fun ile ẹjọ, bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkandinlọgbon ati ọgbọn ọjọ, osu kẹrin, ọdun 2024.

Lẹyin igbẹjọ naa, agbẹjọro ijọba, Rotimi Jacobs sọ pe ẹsun onigba mejila ni wọn fi kan Ahmed, ṣugbọn to ni olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi nigba ti wọn ka a si leti.

Ninu ọrọ agbẹjọrọ Ahmed, Kehinde Ẹlẹja, o sọ pe ilana ti ile ẹjọ gbe kalẹ dara, ati pe ile ẹjọ ti ṣe ipinnu lati ma jẹ ki ẹjọ naa falẹ.

Adajọ ti sun igbẹjọ naa si ọjọ Kọkanddinlọgbọn ati ọgbọn ọjọ oṣu Kẹrin.