Ọ̀jọ̀gbọ́n fásítì Unical tí wọ́n fẹ̀sùn ìyọnilẹ́nu fún ìbálópọ̀ kàn ní òun ò jẹ̀bi ẹ̀sùn náà

Aworan Cyril Ndifon

Oríṣun àwòrán, UNIVERSITY OF CALABAR/ICPC

Ọjọgbọn Cyril Ndifon ti fasiti Unical ti ajọ ICPC fẹsun ìyọnilẹ́nu Ibalopọ s'awọn akẹkọọ rẹ ti sọ fun ile ẹjọ giga niluu Abuja wi pe ko si ọrọ ninu ẹsun ti wọn fi kan oun.

Eyi túmọ si pe olupẹjọ ko ni ẹri to daju pe lootọọ ni o ṣe awọn ohun ti wọn ni pe oun ṣe.

Ajọ ICPC fi ẹsun kan Ọjọgbọn Ndifon to jẹ ọgagba ẹka ẹkọ nipa òfin tẹlẹ ri ni fasiti Unical pe o ṣe iyọlẹnu lati ni ibalopọ pẹlu akẹkọọ rẹ kan ti i ṣe ọmọ ọdun mejilelogun.

Ileẹjọ sọ pe ki wọn maa fi orúkọ akẹkọọ naa han wi pe ki wọn kan pe e ni TKJ.

Agbẹjọro Ndifon, Sunny Anyanwu naa n jẹjọ lori ẹsun naa lẹyin ti ICPC sọ pe o dunkooko mọ TKJ pe ki o ma sọ nkan kan ti ajọ ICPC ba beere ọrọ lọwọ rẹ.

Amọ, nínú ẹjọ ti agbẹjọro Joe Agi (SAN) to duro fun Ndifon nile ẹjọ sọ pe ẹrí ti ajọ ICPC mu wa fihan pe awọn ọrọ atẹjiṣẹ laarin Ndifon ati TKJ ko ju ọrọ to waye laarin ololufẹ meji lọ.

Ṣaaju ni ICPC sọ nile ẹjọ pe Ọjọgbọn Ndifon ni fidio ihoho eeyan lori foonu rẹ eleyii ti ti TKJ naa wa ninu rẹ.

Agbẹjọro ni nitori ICPC n wa ọna lati wa ẹsun si onibara oun lẹsẹ lo jẹ ki wọn gba foonu rẹ lai gbaṣẹ lati ile ẹjọ gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ.

Agi tun rọ ile ẹjọ lati yi ẹjọ naa danu.

O ni TKJ ko si lara awọn to kọkọ fẹsun kan Ndifon lọdọ ICPC.

Agi tun sọ pe fifi fidio ati fọto ìhoho ranṣẹ kii ṣe ohun to yẹ ki ile ẹjọ maa jokoo le lori tori ẹka 26(2) ati 61(3) ajọ ICPC ṣalaye ẹni to le pe ẹjọ ti iru nkan bayii ba ṣẹlẹ.

Bakan naa ni agbẹjọro Agi tun sọ pe adajọ James Omotoso ko lasẹ lati dari igbẹjọ naa.

Bi ọrọ naa ti ṣẹlẹ ree

Ni oṣu Kẹjọ ọdun 2023, ni iroyin kan jade pe awọn akẹkọọ imọ nipa ofin ile ẹkọ gíga fasiti Unical ṣe ifẹhonuhan tako Ọjọgbọn Ndifon lori ẹsun pe o n ṣe iyọlẹnu ibalopo s'awọn akẹkọọbinrin.

Ẹsun yi lo jẹ ki awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa jawe gbele ẹ fun Ọjọgbọn naa ti wọn si bẹrẹ iwadii.

Ndifon ni irọ ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun, ati wi pe awọn ti ko nifẹ oun lo wa ni idi ọrọ naa.

Amọ, ajọ ICPC dasi ọrọ naa, wọn si gbe Ọjọgbọn Ndifon lọ si ile ẹjọ ni oṣu Kẹwaa ọdun 2023 lori ẹsun onikoko mẹrin.