Ọkùnrin kan gbé iléeṣẹ́ tẹ́tẹ́ re ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ní àṣìṣe ni N510bn tó jẹ

Aworan iléeṣẹ́ tẹ́tẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọkunrin kan niluu Washington DC lorilẹ ede Amẹrika to ti lero pe oun ti di ọlọla lẹyin to jẹ tẹtẹ owo to le ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira, N510bn ti gbe ileeṣẹ tẹtẹ Powerball and DC Lottery re ile ẹjọ́ lẹyin ti wọn sọ pe aṣiṣe lo mu awọn tẹ nọmba rẹ jade pe o jẹ owo naa.

Ọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ John Cheeks sọ pe niṣe ni pajapaja mu oun lara nigba ti oun ri pe tikẹẹti oun jẹ owo gọbọi naa ni oṣu Kinni ọdun 2023.

Amọ, nigba ti o mu tikẹẹti naa de ọfiisi ileeṣẹ tẹtẹ ọhun, wọn ni ko si ohun to jọ bẹẹ.

"Ọkan lara awọn aṣoju ileeṣẹ tẹtẹ ọhun sọ pe tikẹẹti ni ko dara pe ki n lọ sọnu," Cheeks ṣalaye fun BBC.

Eyi gan un lo jẹ ki Cheeks lọ gba amofin.

Ni bayii, o ti gbe ileeṣẹ tẹtẹ naa lọ si ileẹjọ, o si n beere fun owo gbamabinu ati ele lori N510bn naa.

"Aṣiṣe airotẹlẹ"

Gẹgẹ bi iwe olujẹjọ ṣe sọ, ileeṣẹ Powerball ati agbaṣẹṣe ileeṣẹ tẹtẹ, Taoti sọ pe aṣiṣe naa waye latari ẹrọ tawon n lo ti ko ṣiṣẹ daadaa.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun sọ pe ni ọjọ kẹfa oṣu Kinni ọdun 2023 to jẹ ọjọ ti Ọgbẹni Cheeks ra tikẹẹti rẹ lawọn n ṣe àyẹwò ẹrọ itakun agbaye ileeṣẹ naa.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iléeṣẹ́ naa fikun ọrọ rẹ pe nọmba tikẹẹti Cheeks wa lara awọn nọmba t'awọn fi ayẹwo lọjọ naa.

Wọn ni àwọn nọmba yii ti wa lori itakun ayelujara awọn fun ọjọ mẹta to fi di ọjọ kẹsan an oṣu Kinni.

Ileeṣẹ tẹtẹ Powerball ati agbaṣẹṣe Taoti kọ lati da BBC lohun lori ọrọ naa.

Ẹsun onikoko mẹjọ ni Ọgbẹni Cheeks fi kan ileeṣẹ tẹtẹ yii bẹrẹ lati aimu adehun ṣẹ, aika-nkan-si, mimu ẹni jiya si ara, to fi mọ ẹsun jibiti.

Agbẹjọro Cheeks, Richard Edwards sọ pe niwọn igba ti tikẹẹti Cheeks ti wa ni ibamu pẹlu nọmba ti ileeṣẹ tẹtẹ naa gbe jade, o lẹtọọ lati gba owo tabua yii.

Bi bẹẹ kọọ, agbẹjọro Cheeks ni o lẹtọọ lati gba owo gba mabinu fun iwa aibikita ti ileeṣẹ tẹtẹ naa hu.

"Ẹjọ ti a pe n beere ibeere lori iduro daadaa ati isotitọ awọn ileeṣẹ onitẹtẹ pẹlu iru aṣiṣe ti ileeṣẹ Powerball and DC Lottery sọ pe o ṣẹlẹ yii," agbejoro Evans lo sọrọ yii fun BBC.

Ọgbẹni Cheeks sọ fun BBC pe "mo mọ wi pe idajọ ododo yoo waye," o tun fikun ọrọ rẹ pe owo yii yoo mu igba ọtun ba igbe aye oun ati ẹbi oun.

Erongba Ọgbẹni Cheeks ni lati ṣi banki ti yoo maa ran awon eeyan to n wale lọwọ, ti ba jare nile ẹjọ.

Wọn ti sun igbẹjọ si ọjọ ketalelogun oṣu Keji ọdun yii.