A kò ní padà sẹ́yìn lórí ìgbésẹ̀ àti mú àyípadà rere bá Nàìjíríà - Tinubu

Aworan Aare Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook

Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe oun ko nii boju wẹyin wo iya ti awọn ọmọ Naijiria n jẹ lori ọwọngogo to n ṣẹlẹ lasiko yii, nitori pe ọna lati mu ayipada rere ba orileede ni.

O ni igbesẹ ati ilana ti ijọba gbe lori ohun to mu ki araalu maa koju iṣoro ati ipenija loriṣiriṣi jẹ eyi ti yoo mu Naijiria bọ sipo to yẹ ko wa.

Aarẹ Tinubu lọ sọrọ yii lasiko to n gba ikọ ajọ Corporate Council on Africa (CCA) ti alakoso agba wọn, Florizelle Liser lewaju fun lalejo nile agbara tiliu Abuja lalejo l’Ọjọbọ, ọsẹ yii.

Nibẹ ni Tinubu ti sọ pe ohun to da oun loju pupọ ni pe gbogbo iṣoro ati ipenija ti araalu n koju yoo dopin laipẹ, ti gbogbo araalu yoo si rẹrin ayọ.

Latigba ti Aarẹ Tinubu ti kede yiyọ owo iranwọ ori epo rọbi lọjọ to gba ijọba, ti owo naira si ti bẹrẹ sii lọ soke si owo dọla ni awọn araalu ti n pariwo ebi.

Ṣugbọn ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Tinubu sọ pe bo tilẹ jẹ pe ipenija nla ni Naijiria ati araalu n koju lasiko yii, ṣugbọn sibẹ, o ni ayọ n bọ laipẹ.

“Inu mi dun lati gba ajọ yin lalejo, ati pe ajọ yin nifẹ si gbogbo ẹka eto ọrọ aje orileede Naijiria. A wa ni aarin meji ipenija to le tun orileede wa ṣe.

“A ti n la a ja, ko si iyemeji, ṣugbọn a ko nii pada sẹyin.

“A ti pe ara wa nija, a si nigbgagbọ pe a maa bori awọn ipenija wọnyi. Mo ni iwa ‘mo le ṣe’ ti yoo ja si ‘a gbọdọ ṣe’. A ni ikọ to dara, ti a si gbọdọ ni afojusun lati de ilẹ ileri wa.”

Ẹ fọkan balẹ, owo naira yoo lagbara sii laipẹ - CBN

Aworan Yemi Cardoso

Oríṣun àwòrán, Yemi Cardoso/X

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa, Gomina ile ifowopamọ agba Naijiria, Yẹmi Cardoso ti rọ gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ lati ṣe suuru, ki wọn si fọkan wọn balẹ lori ọwọngogo to wa nita.

Cardoso sọ pe banki agba Naijiria ti n ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe owo Naira lagbara ju bo ṣe wa lọ.

Gomina Cardoso sọrọ yii nibi eto idanilẹkọọ ita gbangba to waye ninu gbọngan CBN Centre of Excellence ti fasiti ilu Ibadan l’Ọjọbọ to kọja.

Nibẹ lo ti fi ye gbogbo ọmọ Naijiria pe gbogbo igba ti owo Naira ba ti n koju iṣoro ati ipenija, banki CBN naa n koju iṣoro ati ipenija pẹlu.

Cardoso ti Ọmọwe Usman Opanachi to jẹ alakoso lẹka eto ilana owo ṣoju fun ninu ọrọ rẹ ṣalaye pe

“Nigbakugba ti ipenija ba ti ba owo naira, CBN naa ti wa ninu ipenija niyẹn. A ti n ṣiṣẹ lọsan ati lori lati koju awọn ipenija yii, ti a si nigbagbọ ati ireti pe gbogbo rẹ yoo wa si opin.

“Paṣipaarọ owo wa lo ba gbogbo ẹka patapata. Paṣipaarọ naa ti mu ki ọwọngogo ba gbogbo nnkan. Paṣipaarọ yii ni iṣoro ti a ni.

“O ti wa nibẹ tipẹ, banki apapọ si ti gbe oriṣiriṣi ilana kalẹ lati yanju awọn iṣoro wọnyi. Awọn ilana ọhun si ti mu iyanjusi igba diẹ wa.

“CBN kọ ni a ti n tẹ tabi pin owo dọla. Owo naira nikan ni a n ṣe jade. Erongba wa si ni pe awọn ilana wa yii yoo din awọn iṣoro wọnyi ku.”