Iléẹjọ́ ní kí wọ́n lọ yẹgi fún Pásítọ̀,èèyàn márùn-ún míì to fọ báńkì méjì

Ileẹjọ giga kan ni ilu Akure ti dajọ iku fawọn eeyan mẹfa kan ti wọn jẹbi ẹsun idigunjale.
Lọdun 2011 ni wọn kopa ninu idigunjale yi ni ilu Akure ati Idanre.
Ninu awọn ọdaran ti wọn dajọ iku fun yi la ti ri Pasitọ kan Adewale Adelu ati awọn marun un mii – Ikechuckwu Maduagwu, Fayemi Olubusuyi, Ropo Adeleye, Dele Otopka, ati Bayo Omotosho.
Ile ẹjọ gbe idajọ kalẹ pe wọn jẹbi ẹsun idigunjale nigba ti wọn kọlu awọn banki kan to wa ni Akure ni ọjọ Kọkandinlogun oṣu Kọkanla ati lọjọ Kẹjọ oṣu Kejila ni Idanre.
Ọwọ awọn agbofinro nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa tẹ wọn ti wọn si ko wọn lọ siwaju ile ẹjọ.
Lọjọ Iṣẹgun ni ile ẹjọ gbe idajọ kalẹ.
Ni igba ti igbẹjọ bẹrẹ wọn fi ẹsun onigun mẹrin kan awọn ọdaran yi eleyi to da lori igbimọran pọ lati hu iwa aburu,idigunjale,nini nkan ija oloro lọwọ ti wọn si pada ko wọn lọ si ọgba ẹwọn Olokuta.
Agbẹjọro to fẹsun kan wọn F.K Salami sọ fun ile ẹjọ pe awọn ọdaran yi ''gbimọran pọ lati digunjale ni opopona Oyemekun Akure pẹlu ibọn AK47, ado oloro ati awọn nkan mii ''
O tẹsiwaju pe wọn ''ji ọgbọn miliọnu Naira ati foonu oriṣiriṣi to fi mọ awọn nkan olowo iyebiye mii''
“Awọn ọdaran naa tun ṣe ikọlu si ile ifowopamọ First Bank to wa ni opopona Yaba ni Idanre ni ago meji ọsan ọjọ Kẹjọ oṣu Kejila 2011 nibi ti wọn ti ji miliọnu mẹrin Naira gbe''
Olupẹjọ naa sọ pe ''ẹsun ti wọn fi kan wọn yi tako abala ofin orileede Naijiria '6b, 1 2a, ati b' to niṣe pẹlu nkan ija oloro
Awọn igun mejeeji wi atotonu wọn niiwaju adajọ ti wọn si pe awọn eeyan lati wa jẹri.
Nigba ti yoo gbe idajọ kalẹ, adajọ Yemi Fasanmi lọjọ Isẹgun sọ pe olupẹjọ fi ẹri ti ko lẹja n bakan ninu kin ọrọ wọ lẹyin.
O ni awọn ọdaran naa lẹnu wọn ko lori ijẹwọ ti wọn jẹwọ lori kikopa ninu idigunjale naa.
Tori naa adajọ gbe idajọ kalẹ to si sọ pe ki wọn lọ yẹgi fun awọn ọdaran yi lọkọọkan lori ọkọọkan ẹsun ti wọn fi kan wọn.















