Bí wọn kò ṣe mú mi fún ikọ̀ tó lọ gbá bọ́ọ̀lù China ló jẹ́ kí n yà sídi iṣẹ́ orin kíkọ - Pasuma

Aworan Wasiu Alabi Odetola

Oríṣun àwòrán, Pasuma/INSTAGRAM

Ilu mọn-ọn-ka olori Fuji nni, Wasiu Alabi Ọdẹtọla ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Pasuma ti sọ pe bi wọn ko ṣe mu oun fun ikọ ọjẹ wẹwẹ agbabọọlu Naijiria lọdun 1985 lo fa a toun fi ya sidi iṣẹ orin kikọ.

Pasuma ni bọọlu loun n gba tẹlẹ, toun si wa ninu ẹgbẹ agbabọọlu kan lagbegbe Ṣogunlẹ nipinlẹ Ekoo nigba naa.

Agba olorin Fuji naa lo sọrọ yii nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu gbajugbaja oṣerebinrin nni, Iyabo Ojo laipẹ yii.

O ni bi wọn ko ṣe mu oun mọ ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ti lọ gba idije ife ẹyẹ agbaye ti awọn agbabọọlu tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹẹdogun lọ, eyi to waye lorileede China lo jẹ koun gba kamu pe bọọlu alafẹsẹ gba kii ṣe ọna oun.

O fi kun ọrọ rẹ pe awo orin ti Wasiu Ayinde ṣe, eyi to pe ni ‘Talazo 84’, lo tubọ mu ori oun wu, toun si pinnu lati bẹrẹ orin kikọ.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Lọdun 1984, Alaaji Wasiu Ayinde gbe awo orin to pe ni ‘Talazo ‘84’ jade,. Orin naa si ta kaakiri gbogbo agbaye.

“Idi ree ti mo fi pinnu lati wọnu iṣẹ orin kikọ, bọọlu ni mo n gba tẹlẹ.

“Wọn pe mi wọnu ẹgbẹ CODAK 85 [1985 FIFA U-16 World Championship]. Mo wa lara awọn agbabọọlu mẹrin ti wọn mu ninu ẹgbẹ agbabọọlu kan ti mo wa ni Ṣogunlẹ nigba yẹn.

“O ṣeni laanu pe wọn ko mu mi lọ fun idije ife ẹyẹ agbaye naa, idi ree ti mo fi pinnu pe ki n kuku lọ darapọ mọ awọn olorin.

“Agbabọọlu to dantọ ni mi tẹlẹ. Idi ree ti mo fi wọnu iṣẹ orin. Ṣugbọn ọpẹ ni fun Ọlọrun nitori pe gbogbo rẹ lo ti di itan lonii.”