''Ẹ ró ikọ̀ Amọtẹkun lágbára kí ìṣòro ààbò lè dópin nílẹ̀ Yoruba''

Ìpè ti lọ si ọdọ ijọba Naijiria ni gbogbo ẹka, awọn ọba alade ati gbogbo ọmọ Yoruba pata, pe ki wọn ro ikọ Amọtẹkun lagbara si i, ki iṣoro aabo to mẹhẹ lorilẹ-ede yii le dopin.
Nibi eto aabo kan ti awọn ladelade atawọn alẹnulọrọ nilẹẹ Yoruba, ṣe niluu Ile-Ifẹ l’Ọjọbọ ọsẹ yii ni ipe ọhun ti waye.
Akori eto aabo naa ni wọn pe ni, ‘Kidnapping and Banditry: Overcoming the Twin Menace.’ Eyi ti i ṣe bi wọn yoo ṣe koju iṣoro ijinigbe ati janduku.
Awọn ọba alaye bii Ọọni Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọlọwọ tilu Ọwọ; Alayeluwa, Ọba Ajibade Gbadegẹṣin Ogunoye III, Oṣemawe tilu Ondo; Alayeluwa Ọba Victor Kiladejọ, Deji tilu Akurẹ, Ọwa Ajero ti Ijero-Ekiti, Akarigbo ti Rẹmọ, Olowu ti Owu, Oludo ti Ido-Osun, Aragbiji ti Iragbiji ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn fẹnu ko pe atunṣe aabo gbọdọ waye.
Owo, iwuri, idanilẹkọọ, lilo ilana abalaye ati gbigba awọn eeyan to mọ nipa agbegbe si iṣẹ ni wọn fẹnuko si gẹgẹ bi ọna ironilagbara ikọ alaabo naa.
Ipese ohun eelo ati aaye tawọn ẹṣọ naa yoo ti maa ṣiṣẹ tun jẹ dandan bi wọn ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Tribune
‘Ọba Alaye ti ko ba faramọ ilana Yoruba gbọdọ ṣetan lati fi ipo silẹ’
Awọn agbaagba naa tun sọ pe gbogbo ẹka ijọba gbọdọ mọ riri awọn ọba alade ilẹ Yoruba.
Wọn ni ọba to ba lodi si ilana awọn alalẹ Yoruba gbọdọ ṣetan lati fi ori apeere rẹ silẹ ni.
Gbogbo igbo to wa nipinlẹ kọọkan ni wọn ni kawọn ọba atawọn ọmọ oniluu mojuto, nitori ibẹ lawọn ajinigbe n sa si ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi.
Wọn ni kawọn ọba Yoruba maa ranti, pe Iṣẹṣe ni wọn fi joye, ko yẹ ki wọn gbagbe ilana abalaye wọn.
Ipade yii yoo maa waye latigba-degba bi wọn ṣe fẹnuko.
Ọmọwe Solomon Arase, ọga ọlọpaa tẹlẹ lorilẹ-ede yii ati Araba Ifayẹmi Ẹlẹbuubọn ni wọn da awọn eeyan lẹkọọ lọjọ naa.
Oloye Sunday Adeyẹmọ (Igboho Ooṣa) Iba Gani Adams naa wa nibi apero ọhun.














