Wo ipa tí àdínkù owó lítà kan epo 'diesel' tí Dangote ṣe sí N1,000 yóò ní lórí aráàlú

Oríṣun àwòrán, ALIKODANGOTE/X
O ṣeeṣe ki ọwọngogo nnkan ni orilẹede Naijiria bẹrẹ si maa walẹ laipẹ lẹyin ti ile ifọpo rọbi Dangote to wa nipinlẹ Eko kede adinku owo lita kan epo disu lati N1,200 si N1,000.
Ti ẹ o ba gbagbe, owo epo disu eyi t'awọn ọkọ nla akẹru n lo lọ soke fun bi oṣu meloo kan tori owo dọla ti ijọba fi n gbe epo naa wọle lati ilẹ okeere.
Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti o fi sita lọjọ Ìṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii, ile ifọpo rọbi Dangote kede pe ẹgbẹrun un kan naira loun yoo maa ta jala epo disu kan bayii.
Ni bi ọsẹ mẹta to kọja ni ile ifọpo rọbi Dangote kọkọ ṣe adinku owo epo disu lati N1,600 si N1,200.
"Adinku owo epo 'diesel' yoo jẹ ki ọwọngogo nnkan walẹ"
Ninu atẹjade ti ile ifọpo rọbi Dangote fi sita ọhun ni o ti sọ pe adinku owo epo disu yoo ni ipa to dara ni gbogbo ẹka ọrọ-aje Naijiria.
Ile iṣẹ naa sọ pe adinku owo epo disu yoo jẹ ki nnkan to wọn gogo walẹ ni Naijiria.
Ẹwẹ, alaga ile iṣẹ ifọpo rọbi naa, Alhaji Aliko Dangote ti sọ ṣaaju pe adinku owo epo disu yoo mu iyipada to dara ba ọrọ-aje Naijiria.
"Lai ṣe ani-ani, gbogbo ọja t'awọn araalu n ra lo ti gbowo lori, tori owo epo disu t'awọn ọkọ akẹru to n ko ọja fawọn ontaja n lo ti pọju.
Amọ, a kọkọ bẹrẹ pẹlu adinku owo epo disu lati N1600 si N1,200.
Nnkan ti bẹrẹ sí ni yatọ diẹdiẹ lẹyin ti a ṣe adinku yii.
Ni bayii, owo ọkọ ti wọn fi n ko awọn nnkan ti a n pese ni Naijiria bii irẹsi, ẹwa, agbado at'awọn nnkan mii yoo walẹ tori owo epo disu ti dinku.
Eyi yoo jẹ ki ọwọngogo nnkan walẹ kaakiri orilẹede Naijiria.
O dami loju pe, nigba ti ajọ NBS to n ṣe iṣiro data ni Naijiria yoo ba tun gbe nọmba mii jade lori ọwọngogo nnkan, nọmba naa gbọdọ lọ silẹ ju bi o ṣe wa bayii.
Ọpọ eeyan ni ko mọ eleyii.
Nitori naa, ọkọọkan la a yọ ẹsẹ lẹku ni ọrọ naa da bayii.
Mo ṣi gbagbọ wi pe ijọba n gbiyanju lati sọ igba dẹrọ fun araalu," Dangote lo sọ bẹẹ.















